Yoruba Àwọn abẹ́rẹ́ àjẹsára wà láti dáàbò bo ìwọ, àwọn tí ...
Transcript of Yoruba Àwọn abẹ́rẹ́ àjẹsára wà láti dáàbò bo ìwọ, àwọn tí ...
Ohun gbogbo ti o ni lati mọ nipa awọn abẹrẹ ajẹsara Covid-19:
Awọn otitọ ni kankan:
Awọn abẹrẹ ajẹsara ngba ẹmi la.
Awọn abẹrẹ ajẹsara Covid-19 ti kun oju oṣuwọn ailewu ti o le julọ.
Awọn abẹrẹ ajẹsara ndaabo bo gbogbo ilu rẹ.
Ko si ẹri pe awọn abẹrẹ ajẹsara Covid-19 ni ipa lori agbara ibimọ.
Awọn akitiyan agbaye nla ni o ti awọn abẹrẹ ajẹsara Covid-19 lẹyin.
Ko si eroja ara eniyan tabi ti ẹranko, tabi ẹyin ninu atokọ awọn eroja awọn abẹrẹ ajẹsara Covid-19.
Awọn abẹrẹ ajẹsara wa lati daabo bo iwọ, awọn ti o fẹran ati awọn eniyan ti o wa ni ayika rẹ.
Yoruba
Ohun gbogbo ti o ni lati mọ nipa awọn abẹrẹ ajẹsara Covid-19:
! Gba awọn otitọ lati awọn orisun ti o ṣe e gbarale, ti o ṣe e fi ọkan tan.
! Ṣe agbekalẹ akojọpọ awọn orisun yẹn: awọn wẹbsaiti fun NHS, Ajọ Ilera Agbaye (WHO), ati Ẹgbẹ Alagbeelebuu Pupa Ilẹ Gẹẹsi (a jẹ ajọ kan ti ko fi si apakan ti a fi ara ji fun riro awọn eniyan lagbara pẹlu awọn otitọ).
! Lo akoko lati ka nipa ki o si loye awọn abẹrẹ ajẹsara Covid-19. Ti ohunkohun ba yẹ fun alekun ipele itọju ati agbeyẹwo, ilera rẹ ni o jẹ.
! Ti o ba ka nnkan kan lori awọn ojuko iroyin igbalode tabi ninu ijiroro ẹgbẹ ori WhatsApp kan ti ko da ọ loju, gbe igbesẹ kan pada sẹyin ki o si ṣe iwadii nipa rẹ funraarẹ.
! Awọn iṣe wa nni ipa lori awọn ẹlomiran, ni awọn ọna pataki.
Ranti:
Ohun gbogbo ti o ni lati mọ nipa awọn abẹrẹ ajẹsara Covid-19:
Awọn Abẹrẹ Ajẹsara: - O to miliọnu mẹta ẹmi ti awọn abẹrẹ ajẹsara
ngbala ni Ilẹ Gẹẹsi ati kari aye ni ọdọọdun.
- Nitori awọn abẹrẹ ajẹsara, awọn aisan bi ilẹẹgbona, rọpa-rọsẹ ati arun ipa ko si mọ tabi wọn ti ṣọwọn gidigidi.
- Ti a ba gba abẹrẹ ajẹsara, a tun ndaabo bo ẹnikan ti o ni ailera ju wa lọ, ti o le ma le gba abẹrẹ ajẹsara funraarẹ (fun apẹẹrẹ awọn ti ara wọn ko da tabi ti eto ajẹsara ara wọn mẹhẹ).
Ailewu abẹrẹ ajẹsara Covid-19: - Ko si bi wọn ti le fi ọwọ si awọn abẹrẹ
ajẹsara naa fun ọpọlọpọ miliọnu awọn eniyan ti iyemeji kankan ba wa nipa ailewu, pipeye tabi ṣiṣe iṣẹ rẹ.
- Awọn oṣuwọn yii ni a gbe kalẹ lati ọwọ Ajọ Ti O Nbojuto Awọn Oogun Ati Awọn Ohun Elo Itọju Ilera [Medicines and Healthcare products Regulatory] ti o nrii daju pe gbogbo oogun ti a nlo ni Ilẹ Gẹẹsi wa ni ailewu.
- Wọn dan abẹrẹ ajẹsara Oxford/AstraZeneca wo lara ẹgbẹrun mọkanla eniyan o le. Wọn dan abẹrẹ ajẹsara Pfizer/BioNTech wo lara ẹgbẹrun mẹtalelogoji ati abọ eniyan.
Awọn orisun
NHS – https://www.nhs.uk/conditions/coronavirus-covid-19/coronavirus-vaccination/coronavirus-vaccine/?gclid=EAIaIQobChMIybeg86O87QIVVOvtCh00OAFSEAAYASAAEgKs3PD_BwE Ajọ Ilera Agbaye (WHO) – https://www.who.int/emergencies/diseases/novel-coronavirus-2019/covid-19-vaccines UK – https://www.gov.uk/coronavirus Scotland – https://www.gov.scot/coronavirus-covid-19/ Wales – https://gov.wales/coronavirusNorthern Ireland – https://www.nidirect.gov.uk/campaigns/coronavirus-covid-19
Idagbasoke abẹrẹ ajẹsara Covid-19: - Ko si abala kankan ti a fo lara igbesẹ naa.
- Ohun mẹta ni o jẹ ki idagbasoke abẹrẹ ajẹsara ya kankan: owo nla, awọn alekun ohun elo, ati ọpọlọpọ awọn oniṣẹ iwadii. Igbesẹ dagbasoke abẹrẹ ajẹsara Covid-19 ni mẹtẹẹta.
- Ko si abẹrẹ ajẹsara miran ti o tii ni iru atilẹyin agbaye iru eyi ri.
- Afojusun kan ni agbaye ni – lati fi opin si itankalẹ kokoro arun apani yii – nitori naa awọn ijọba kaakiri agbaye ṣe agbekalẹ alekun owonaa.
Bi awọn abẹrẹ ajẹsara Covid-19 ti nṣiṣẹ: - Awọn abẹrẹ ajẹsara naa maa nṣiṣẹ nipa
fifi ami ranṣẹ si eto ajẹsara ara rẹ lati ṣẹda awọn olugbeja ti o nba kokoro arun naa ja.
- Wọn kii yi DNA rẹ pada.
- Ko si ẹri pe wọn nni ipa lori agbara ibimọ.
Awọn eroja abẹrẹ ajẹsara Covid-19: - Wọn o ni eroja ara eniyan kankan,
eroja ẹranko tabi ẹyin.
Iwoye kan ti o jinlẹ sii…