Ipa Tí Ogun Ẹnu ń Kó Nínú Àwùjọysan.org/umgt/uploaded/184_Ipa_Ti_Ogun.pdf · 78 Ipa Tí...

28
Ipa Tí Ogun Ẹnu ń Kó Nínú Àwùjọ Fasehun Mercy Ayọ̀, Ph.D. Department of Yorùbá Adéyẹmí College of Education Ondo, Ondo State [email protected] Àṣamọ̀ Ọ kan lára ogun tí ó ń bá ọmọ ènìyàn jà láìfura ni ogun ẹnu. Ní ò ̣ pò ̣ ìgbà ni àìlóye tàbí àìnáání ipò àti ipa tí ẹnu ń kó ní ayé ̣dá àti àwùjọ máa ń fa wàhálà àti ogun ayó ̣ nijà. Ènìyàn tàbí ìlú tí kò ní idà, ogun ẹnu ni wó ̣n i í pani. A tilẹ̀ lè sọ wí pé nípasẹ̀ ò ̣ rò ̣ ẹnu gan-an ni ogun àdá àti ò ̣ kò ̣ ti ń sẹ́yọ. Ogun ẹnu fẹ́rẹ̀ burú ju ogun idà lọ nítorí pé agbára ń bẹ nínú ò ̣ rọ̀ ẹnu. Ohun tí pépà yìí gbéyẹ̀wò ni agbára tí ń bẹ nínú ò ̣ rò ̣ ẹnu àti ohun ìjìnlẹ̀ tí ó rò ̣ mó ̣ àṣìlò ẹnu. Àkóyawó ̣ àlàyé nípa ogun ẹnu àti oríṣìíríṣìí tí a lè tó ̣ kasí pẹ̀lú ò ̣ nà tí ó ń gbà jani ni pépà yìí tẹpẹlẹ mó ̣. Onírúurú ò ̣ nà tí a lè i borí ogun ẹnu ni pépà yìí tún mẹ́nubà. Détà tí a lò fún iṣẹ́ yìí ni ẹsẹ ifá, òwe, orin, ò ̣ rò ̣ sísọ àti àwọn èdè ojoojúmó ̣ pẹ̀lú eré-onítàn àpilẹ̀kọ méjì: Ẹfúnróyè Tinúubú àti Ẹfúnṣetán Aníwúrà tí ó jẹ́ ìtàn gidi. Àbájáde pépà yìí ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé bí ogun idà ṣe lè pani náà ni ogun ẹnu lè pani tí ó sì lè run odidi ìlú. Kókó ọ̀ rọ̀: Ogun, Ẹ nu, A wù jọ .

Transcript of Ipa Tí Ogun Ẹnu ń Kó Nínú Àwùjọysan.org/umgt/uploaded/184_Ipa_Ti_Ogun.pdf · 78 Ipa Tí...

Page 1: Ipa Tí Ogun Ẹnu ń Kó Nínú Àwùjọysan.org/umgt/uploaded/184_Ipa_Ti_Ogun.pdf · 78 Ipa Tí Ogun Ẹnu ń Kó Nínú Àwùjọ ọ̀rọ̀ a máa bẹ tı́ kı̀ ı́ sáyè,

Ipa Tí Ogun Ẹnu ń Kó Nínú Àwùjọ

Fasehun Mercy Ayo, Ph.D. Department of Yorùbá

Adéyẹmí College of Education Ondo, Ondo State

[email protected]

Àṣamo O� kan lára ogun tí ó ń bá ọmọ ènìyàn jà láìfura ni ogun ẹnu. Ní opo ìgbà ni àìlóye tàbí àìnáání ipò àti ipa tí ẹnu ń kó ní ayé edá àti àwùjọ máa ń fa wàhálà àti ogun ayonijà. Ènìyàn tàbí ìlú tí kò ní idà, ogun ẹnu ni won �i í pani. A tile lè sọ wí pé nípase oro ẹnu gan-an ni ogun àdá àti oko ti ń seyọ. Ogun ẹnu fere burú ju ogun idà lọ nítorí pé agbára ń bẹ nínú oro ẹnu. Ohun tí pépà yìí gbéyewò ni agbára tí ń bẹ nínú oro ẹnu àti ohun ìjìnle tí ó ro mo àṣìlò ẹnu. Àkóyawo àlàyé nípa ogun ẹnu àti oríṣìíríṣìí tí a lè tokasí pelú onà tí ó ń gbà jani ni pépà yìí tẹpẹlẹ mo. Onírúurú onà tí a lè �i borí ogun ẹnu ni pépà yìí tún menubà. Détà tí a lò fún iṣe yìí ni ẹsẹ ifá, òwe, orin, oro sísọ àti àwọn èdè ojoojúmo pelú eré-onítàn àpilekọ méjì: Ẹfúnróyè Tinúubú àti Ẹfúnṣetán Aníwúrà tí ó je ìtàn gidi. Àbájáde pépà yìí �ìdí re múle pé bí ogun idà ṣe lè pani náà ni ogun ẹnu lè pani tí ó sì lè run odidi ìlú. Kókó oro: Ogun, Enu, A� wujo.

Page 2: Ipa Tí Ogun Ẹnu ń Kó Nínú Àwùjọysan.org/umgt/uploaded/184_Ipa_Ti_Ogun.pdf · 78 Ipa Tí Ogun Ẹnu ń Kó Nínú Àwùjọ ọ̀rọ̀ a máa bẹ tı́ kı̀ ı́ sáyè,

77

Yorùbá: Journal of the Yorùbá Studies Association of Nigeria (Vol. 9 No. 1)

Ìfáárà

O� rısa ni enu. Bıbo ni o ye kı a maa bo o nıtorı pe orısıırısıı

ohun ati ıpede ni o n jade nıbe. Ohun ati ıpede yıı le je

dıdara tabı buburu. E� yı tı o ba dara a maa fa obı yo lapo, eyı

tı o ba buru a sı maa yo ida lako. O� ro nı mımo on so, o sı nı

mımo on gbo. Orısıırısıı ısowo-soro ati ısowo-lo-ede ni o wa

bakan naa (O� gunyemı 1998:22). O� wuye, asoro-ıso bı oro.

Eyin lohun, bı o ba ti bo ko se e ko mo. I�dı nıyı tı enıyan �i

gbodo ronu kı o to so oro jade lenu. I�sowo-soro maa n �i iru

eda tı enıyan je han. O� ro enu a maa buyı kun eni, o sı le ba ti

enıyan je. A le se enıyan nı suta laılo ada ati ıbon. Iku ati ıye

n be nınu agbara ahon ati enu. I�basepo to gborın wa laarin

enu, ahon ati etı tı o �i je pe nı kete tı etı ba ti gbo oro yala

rere tabı buburu ni ayıpada tabı ımolara yoo ti de ba emı.

I�dı nıyı tı awon Yoruba se n so wı pe “oro lomo eletı n je” ati

pe “bı etı ko gbo yınkın, inu kı ı baje”.

Ẹnu

I�we O� we nınu I�we Mımo awon omoleyın-Jesu, orı

kejıdınlogun, ese keje (I�we O� we 18:7) so pe:

Enu omugo ni ıparun re ete re sı ni panpe okan re

E� da maa n so oro odı laıfura tabı laımoomo nıgba mııran.

O� po ıgba sı ni ıbınu, ıgberaga, anıkanjopon, ıkorııra, iyemejı

ati aımokan maa n je kı a so oro odı tı o le �i ogun jani.

Yoruba bo, won nı enu ara eni la �i ı ko meeje. Nıgba mııran

Page 3: Ipa Tí Ogun Ẹnu ń Kó Nínú Àwùjọysan.org/umgt/uploaded/184_Ipa_Ti_Ogun.pdf · 78 Ipa Tí Ogun Ẹnu ń Kó Nínú Àwùjọ ọ̀rọ̀ a máa bẹ tı́ kı̀ ı́ sáyè,

78

Ipa Tí Ogun Ẹnu ń Kó Nínú Àwùjọ

oro a maa be tı kı ı saye, opo ıgba ni aye maa n be tı kı ı soro.

E� yı ja sı pe kı ı se gbogbo ıgba ati gbogbo ibi ni a ti le soro

nıtorı pe agbara n be nınu oro. Gbogbo ohun tı oju ba rı ko

ni enu n so. Boju ba rı enu a dake. E� yı tı enu ba rı tı ko ye kı

o so, sugbon tı o taku pe dandan oun yoo so o a maa fa ogun

ba enıyan. Omo tı ko ba mo oro so tabı tı oro enu re ko dara

ni awon Yoruba gba pe awon obı re ko jo lenu nı kekere

nıtorı pe

Enu nı ı pani Enu nı ı lani Eyın nı ı basırı enu A� telese nı ı basırı ese A� ımenu menu A� ıfete mete Lo dıfa fun omo ıya mefa To ku soko egbaafa.

Bı oju ba rı tı ko dake, ogun enu nı �i ı pani. Bı a se le

�i enu pebi sı enıyan ni a se le �i pe ire. A� se n jade lenu, epe

sı n jade nıbe. Enu a maa tun nnkan se, bee ni o sı n da

nnkan ru. Onıruuru enu ni a le tokası nıpase oro tı o ba n

jade nıbe bı i enu egan, enu ısokuso, enu ete, enu epe, enu

iro, enu ase, enu mımo, enu aımo, enu iyo, enu dıdun ati bee

bee lo. A le �i enu pebu alaafıa, a sı le �i da ogun sıle. Enu tı a

�i n pe Ade gun naa la �i pe Ade o gun. E� yı tumo sı pe enu pe

mejı fun ire ati ibi gege bı orin ifa kan tı a gbo lenu abena

ımo (babalawo) se toka sı i pe:

Lílé: Enu won lofa Enu won loje

Page 4: Ipa Tí Ogun Ẹnu ń Kó Nínú Àwùjọysan.org/umgt/uploaded/184_Ipa_Ti_Ogun.pdf · 78 Ipa Tí Ogun Ẹnu ń Kó Nínú Àwùjọ ọ̀rọ̀ a máa bẹ tı́ kı̀ ı́ sáyè,

79

Yorùbá: Journal of the Yorùbá Studies Association of Nigeria (Vol. 9 No. 1)

A kıı belenu mejı dowo po Ko ma hun ni (Awo Awogbola, 2017)

O� ro “hihun ni” yıı ni ogun tı o n je jade nınu ayolo oke yıı. A

le topase eyı de inu owe Yoruba tı o so pe:

Oju la rı O� re ko denu Sasa enıyan nı ı feni leyın ba o sı nıle Taja teran nı ı feni loju eni

A� won enıyan kan wa tı o je pe oto ni ohun tı won maa wı

loju eni, oto ni eyı tı won maa se leyın eni.

E� we, bı a ba soro, o ye kı a maa yan an kı o ma ba a

dogun funni nıtorı pe “a soro ı yanro lo pelenpe ısaaju, to nı

igba wuwo ju awo lo. Bı apeere, tı enıkan ba fe rin ırınajo tı

o wa n dagbere fun ore tabı alabaagbe re pe “Maa lo sugbon

n o nı ı de”. Oluwa re le lo kı o ma de loooto nıtorı pe oro ti

dapo mo afefe ati ase. Nı opo ıgba ni agba tı o ba wa nıtosı

eni to so oro yıı yoo ti tete so fun oluwa re pe kı o pa enu re

da pe yoo lo ire, yoo bo ire. Ohun tı o ye kı eni naa so

lakooko ni pe

Mo maa lo Sugbon n o nı ı de lonıı Yoo di ola tabı otunla

Odu Ifa I�worıwonda tile �i yeni pe bı enıyan ba n �i

enu pere fun ara re lojoojumo ko sese nılo awure tabı oogun

asela mo. E je kı a wo ohun tı Odu yıı wı:

Page 5: Ipa Tí Ogun Ẹnu ń Kó Nínú Àwùjọysan.org/umgt/uploaded/184_Ipa_Ti_Ogun.pdf · 78 Ipa Tí Ogun Ẹnu ń Kó Nínú Àwùjọ ọ̀rọ̀ a máa bẹ tı́ kı̀ ı́ sáyè,

80

Ipa Tí Ogun Ẹnu ń Kó Nínú Àwùjọ

I�worı lotun un O� gunda losı I�worı wonda Orı aweda o gboogun To ba ti jı Enu nı ı �i n pere funra re Asaolu (1981:54)

E je kı a wo apeere mııran nınu Odu O� gunda mejı, ese

karun-un tı o lo bayıı:

Woroko woroko ni woon roko; Woroko woroko la a rada, Ledıda ledıda n la a ragogo ide, Bı o ba doke, a dokan; A dıa fun O� runmıla, Nıjo tı Ifa n be laarin osıırı, Tı Ifa n be laarin ota, Ifa o pasuwon gbooro Tı yoo kenu ota da sı O� runmıla nı, N� je tonıru tonıyo Enuu won suınsuınsuın, Enuu won Alalubosa alata, Enuu won suınsuınsuın Enuu won. Abımbola (1977:54)

Ese Ifa yıı �ihan pe ohun tı enu n se loro omonıyan ko kere

rara. Tı enu ba n kun enıyan, ohun tı ko dara rara ni. A� feree

je wı pe ıdı nıyı tı Ifa �i kenu ota sınu apo kı won ba le jawo

loro re. Bı aye ba ko enu ti enıkan afaımo kı onıtohun ma

sıse.

Bı a ba mu ado oogun lowo bı a ko ba tıı ran an nıse

pelu oro, ko le sise, nı kete tı oro ba ti dahun lara re ni yoo

Page 6: Ipa Tí Ogun Ẹnu ń Kó Nínú Àwùjọysan.org/umgt/uploaded/184_Ipa_Ti_Ogun.pdf · 78 Ipa Tí Ogun Ẹnu ń Kó Nínú Àwùjọ ọ̀rọ̀ a máa bẹ tı́ kı̀ ı́ sáyè,

81

Yorùbá: Journal of the Yorùbá Studies Association of Nigeria (Vol. 9 No. 1)

dase tı ase yoo sı dahun fun ise tı a ran an. Odu Ifa O� wonrın

mejı, ese karun-un fıdı re mule pe orısa lenu.

Agbongbon, awoo won lode I�loree A� gbayangıdı awo ode I�jesa Okunrin yangıdı yangidi Ni won dı nı atıpa A dıa fun Olooyımefun Nwon nı o boogun ile O� boogun ile Awoo re o fın Nwon nı o boosa oja O� boosa oja Awoo re o da O� osa oja o gba Nwon nı o borı O� borı Orı pa Nwon nı o bole O� bole Ilee lu Nwon nı o bo Olubobotiribo baba ebo Nwon nı enu Enu nı ı je Olubobotiribo baba ebo N� je kın la n bo nı’fe, Enu won Mo fun gba Mo fawo Enu won, Enu won ko mo le rı mi baja Enuu won Abımbola (1968:73-74)

A� yolo oke yıı �ihan pe agbako nla ni eda tı ogun enu ba kolu

ko. E� yı �i han pe a n bo enu araye kı won le baa wı tiwa nıre.

Bı a ba sase repete nıbi ınawo tı a sı pese jıje mımu fun opo

Page 7: Ipa Tí Ogun Ẹnu ń Kó Nínú Àwùjọysan.org/umgt/uploaded/184_Ipa_Ti_Ogun.pdf · 78 Ipa Tí Ogun Ẹnu ń Kó Nínú Àwùjọ ọ̀rọ̀ a máa bẹ tı́ kı̀ ı́ sáyè,

82

Ipa Tí Ogun Ẹnu ń Kó Nínú Àwùjọ

enıyan, aye a fenu sure fun wa. Bı a ko ba pese jıje mımu bı o

ti ye, o le fa ogun enu funni. Orin Ifa kan naa tı a gbo lenu

abena ımo wa tun �i ıdı eyı mule pe:

Enu lo paraba to wo Enu lo pose saa�in Enu ma pamı sonu Nı kekere (Awo Awogbola, 2017)

Gege bı a ti mo pe igi araba ati ose je igi nla tı o lagbara. A sı

le �i awon igi wonyı we eekan ılu bıi Oba, A� are, ıjoye, ati

awon olowo tı ısesı ati ıhuwası won ko te awujo lorun tı

omo araye sı n �i enu buruku kan won. E� yı tı o sı le fa ısubu

won. Bı enu ba le pa awon wonyı, o daju pe ko sı eni tı enu

ko le pa. Bakan naa ni ayolo inu ese Ifa Odu O� tua mejı so pe:

A díá fún Arúgbóbinrin Ife Won ní ó lóṣó Ó lóun ò lóṣó Won ló lájee Ó lóun ò lájee Ó ní àṣẹ nìkan lòun ní Ẹnu nìbà Ẹnu awo làṣẹ Agboola, (1989)

Ohun tı a rı fayo nınu ayolo ese Ifa oke yıı ni pe ohun tı

enıyan ba �i enu ara re so maa n se ju wı pe enıyan loso tabı

nı aje lo.

Ogun Ẹnu

I�we Jakobu orı 3, ese karun-un sı ıkefa, nınu Bıbelı mımo wı

pe:

Page 8: Ipa Tí Ogun Ẹnu ń Kó Nínú Àwùjọysan.org/umgt/uploaded/184_Ipa_Ti_Ogun.pdf · 78 Ipa Tí Ogun Ẹnu ń Kó Nínú Àwùjọ ọ̀rọ̀ a máa bẹ tı́ kı̀ ı́ sáyè,

83

Yorùbá: Journal of the Yorùbá Studies Association of Nigeria (Vol. 9 No. 1)

Bee pelu ni ahon je eya kekere o sı n fohun nla, wo igi nla tı ina kekere n sun jona

Bı ahon se kere to nı eya ara, o kun fun egun oun osusu pelu

ina to n joni lara. Gbogbo ibi la ti n ko adıe ale ni oro ogun

enu je. A� won obı a maa �i ogun enu ba omo won ja, awon

olorı esın naa maa n lo o, awon oloselu a maa �i tako ara

won, bee naa ni awon oga ile ise ko gbeyın nıpa fı�i ogun

enu ja awon omo ise tabı alabaasise kule. Ogun enu a maa fa

ıja lese, o sı maa n baye eni je. O� n ko ıfaseyın ati ırewesı ba

eda. O� n se okunfa ıja esın ati eleyameya. Gege bı Raji

(1991:vi) se so, oro ro wale, o ro kı, o ro ku, o ro ke. O� ro ni a

�i n se ohun gbogbo nıle aye. I�jı loro, o le fe lo nıgbakuugba,

ko sı ibugbe fun ategun. Ko sı ibi tı oro ko le de. E� nıyan le wa

nı E� ko kı o maa foro ranse sı I�kale. E� da to ba rıja alaroka,

ogun enu nı ı ba a fın ra. E� yı sı le seku pani. O� we Yoruba kan

�i ıdı eyı mule pe

Ebo oso se e ru Ebo aje se e ru Ebo alaroka ni ko se e ru Ebo alaroka pani ju ogun oso lo

E� nıyan to ba mejo rıro, tı enu re kı ı duro, o di dandan ko

kagbako ogun enu nıtorı pe ohun tı oju re rı ati eyı tı ko rı ni

yoo maa so.

Ogun enu kun fun onıruuru suta tı a le �i enu se tı a

saba maa n so sıta lati gba ara wa sıle (Adetoye, 2009).

Ogun enu ko mu ohun ıja oloro tı a le �i oju rı bıi ofa, ıbon,

Page 9: Ipa Tí Ogun Ẹnu ń Kó Nínú Àwùjọysan.org/umgt/uploaded/184_Ipa_Ti_Ogun.pdf · 78 Ipa Tí Ogun Ẹnu ń Kó Nínú Àwùjọ ọ̀rọ̀ a máa bẹ tı́ kı̀ ı́ sáyè,

84

Ipa Tí Ogun Ẹnu ń Kó Nínú Àwùjọ

oko, ada ati bee bee lo danı bı ogun gan an funra re. I�lo

agbara aırı ati oro lıle koko lati enu la �i le ja ogun enu lati le

je kı ohun tı a fe se e se nı kıakıa. Mejı lohun: ohun ire ati

ohun ıka. Ohun ıka a maa loro nınu amo ohun ire kı ı loro

nınu. Gege bı a ti salaye saaju pe bı ogun ida se le pani ni ti

enu naa le pa ni. Raji (1991:ix) fıdı eyı mule bayıı pe:

Amuda pewele O� pewele wole I�do�in I�lu tı ko nıda, Ogun ni won �i n para won

E� yı hande nınu orıkı A� kure kedere bayıı:

A� kure olomi mejı O� pejejı lala Omo omuda sıle, Fi ogun enu pani.

Orıkı A� kure yıı �i won han gege bı eni tı o n �i enu jagun. Enu

won mu ju abe lo.

Bakan mejı ni ırısı ogun enu ni ojuwoye awon Geesı.

Won a pe e nı cold war, battle of words tabı hate speech.

A� laye tı won se nıpa re nıyı:

Hate speech is a term which refers to a whole spectrum of negative language, ability, moral or political views, socio-economic class, occupation or appearance… of expression… It often makes violence or prejudicial action. Ogun enu ni a le tumo sı awon ıpede odı nıpa ipa, ıwa oro-ıselu, eto oro aje ati ırısı. Nı opo ıgba ni o maa n fa ogun ati ıja lese.

Page 10: Ipa Tí Ogun Ẹnu ń Kó Nínú Àwùjọysan.org/umgt/uploaded/184_Ipa_Ti_Ogun.pdf · 78 Ipa Tí Ogun Ẹnu ń Kó Nínú Àwùjọ ọ̀rọ̀ a máa bẹ tı́ kı̀ ı́ sáyè,

85

Yorùbá: Journal of the Yorùbá Studies Association of Nigeria (Vol. 9 No. 1)

A� won oloselu, olorogun, onısowo/orogun owo, eleyameya,

orogun ise a maa �i ogun enu ba ara won ja nı opo ıgba. Bı

apeere, oro Fayose sı Buhari nıgba tı o n sojojo tı won gbe e

lo sı ile Amerıka. A ri gbo nınu ıroyın pe Gomına Fayose lerı

pe bı A� are Buhari ba morıbo nınu aare tı o mu un tı o sı de

laaye sı orıleede Naıjırıa, pe se ni oun yoo pokunso. Gomına

Ayodele Fayose ti koko so nıpa Buhari nıgba ıpolongo ıbo

bayıı:

Buhari would likely die in office if elected, recall that Murtala Muhammed, Sani Abacha and Umaru Yar’Adua, all former heads of state from the North West like Buhari, had died in office. O� seese kı Buhari ku sorı alefa bı won ba yan an sıpo, e rantı pe Murtala Mohammed, Sani Abacha ati Umaru Yar’Adua, gbogbo awon A� are ana tı won wa lati ıwo oorun gusu lo ku sorı alefa.

This Day Newspaper, January 19, 2015

Kofeso Wole Soyınka naa ko fe kı Gomına Donald

Trump wole sı ipo A� are ile Amerıka nıgba naa. O� un naa

jagun enu pelu Trump pe bı o ba wole, se ni oun yoo fa ıwe

ırınna oun ya tı oun ko sı nı ı wo ile Amerıka mo toun yoo �i

ku. E� yı �i ıkorııra tı Soyınka nı sı Trump han.

Page 11: Ipa Tí Ogun Ẹnu ń Kó Nínú Àwùjọysan.org/umgt/uploaded/184_Ipa_Ti_Ogun.pdf · 78 Ipa Tí Ogun Ẹnu ń Kó Nínú Àwùjọ ọ̀rọ̀ a máa bẹ tı́ kı̀ ı́ sáyè,

86

Ipa Tí Ogun Ẹnu ń Kó Nínú Àwùjọ

Àwọn Ohun Ìjà Ogun Ẹnu

Onıruuru ni awon ohun ıja ogun enu. Bı a ti rı kumo, oko,

obe, akatapo ati awon ohun ıja ogun oloro mııran ni a tun rı

awon ohun ıja ogun enu bı i oro sakala, orin ati ewı awıse.

A� peere oro sakala nınu ogun enu ni eebu, yeye, oro, apara

ati epe sıse ati efe. O� na ı�inisesın ati ıpegan eni ni yeye ati

efe. O� tile le waye nı ılana epe. Orin yeye je okan lara ohun

ıja ogun enu tı a �i n ru ıbınu eni soke. Orin owe, orin ote,

orin eebu naa je ohun elo ogun enu. A� won ewı awıse maa n

nı awon gbolohun maye nınu. A� peere won ni ofo, ogede,

ayajo ati aasan.

Ogun Ẹnu tí ó jẹ mo O� ro Sísọ lásán

Nınu ıwe ere-onıse Ẹfúnróyè Tinúubú ti Akınwumı

(2009:93), bı awon obayeje agba ılu E� ko ti fe gbe ılu E� ko sı

abe ıjoba geesı ni o mumu laya won. A� mo Tinuubu faake

korı, o ko jale pe ko nıı rı bee. Nıpa bayıı, onıruuru ogun enu

ni won �i ba ara won ja nınu ıwe yıı lati rı eyın Tinuubu.

Baluaye tile so gbangba pe bı won ba �i ogun enu pa

Tinuubu, o dara ju ti ida lo.

Baluaye: O� na mııran wa o. O� na mııran wa daadaa. Ogbon agba. O� ro enu lasan wulo ju tıbon-tetu tı e n wa kiri yıı lo. A� won agba tı won feran E� ko, tı won fee yo o nınu rederede tı o fo rera yıı ni won ran mi. (o.i. 93)

Dosunmu: Èmi fo redẹredẹ rẹra? Balúayé ṣo ẹnu rẹ!

(o.i. 93)

Page 12: Ipa Tí Ogun Ẹnu ń Kó Nínú Àwùjọysan.org/umgt/uploaded/184_Ipa_Ti_Ogun.pdf · 78 Ipa Tí Ogun Ẹnu ń Kó Nínú Àwùjọ ọ̀rọ̀ a máa bẹ tı́ kı̀ ı́ sáyè,

87

Yorùbá: Journal of the Yorùbá Studies Association of Nigeria (Vol. 9 No. 1)

Bı enu awon oba ati ıjoye ılu ko se duro naa ni ti Tinuubu ko

duro tı won sı n tako oro sı ara won. I�ya Tinuubu gba a

nıyanju pe kı o mase ja sugbon Tinuubu ko jale o nı:

Tinuubu: O� un ko o, rara. Ma �i oko mi dona, ojo kan laa yanju re. Boju ba koju aala a maa to. Won pe won nıja ni. Bı won ba ba ılu E� ko je, ejo Oba nıyen, kı ı se temi. Mo fara mo ohunkohun to ba sele sı mi ati oro tı mo nı. O� na to ye omoluabı nıyen. (o.i. 103)

I�ya Tinuubu ro o tıtı pe kı o ro ıgbese re daradara pe

I�ya:

E� ru n ba awon gan an alara, sugbon se o waa dara kı a so pe kı Oba ko oro re je ni?

E� sı tı Tinuubu fun ıya re nıyı:

Hen, eni to ba tole agbon n ko… Beeyan o ba loogun rındo-rındo, ko gbodo je aayan. Oba to ba mase pa, o ye kı o mo ogun n ja (o.i. 103).

Ohun tı o daju ni pe oba ba lorı ohun gbogbo. Sugbon ayolo

oke yıı �i han pe Oba ti koja aye re, o ti gbe iyı re yıraa nıle.

Tinuubu �i enu gba ara re sıle. E� yı tı o �i han wı pe bı ogun

enu se le pani naa ni o le gba ni lowo ogun nıtorı pe enu ara

eni la �i n ko meeje. Nı eyın-o-reyın, Tinuubu pada gbayı

nıtorı pe ko ku enu nıtorı pe aılesoro ni ıbere orıburuku.

Abajo tı Epega (1924) se so nınu okan nınu akojopo ese-ifa

re tı o pe nı ‘O� kanran-E� guntan pe:

Eni owo n ya lı ogun ı gbe

Page 13: Ipa Tí Ogun Ẹnu ń Kó Nínú Àwùjọysan.org/umgt/uploaded/184_Ipa_Ti_Ogun.pdf · 78 Ipa Tí Ogun Ẹnu ń Kó Nínú Àwùjọ ọ̀rọ̀ a máa bẹ tı́ kı̀ ı́ sáyè,

88

Ipa Tí Ogun Ẹnu ń Kó Nínú Àwùjọ

Lojo enıyan tı ko le ja Tı ko le soro Ko nı ı le gbenu aye pe I�ja n sola I�ja n se iyı Alagbara lo ni aye Akin lo ni aye A kı ı rubo fun ojo… (I�la 1-6, 11, 13-14)

Akıwowo (2003:191) tun �i ıdı eyı mule nınu ese-ifa “O� se

sa” pe:

I�ja nıwaju I�ja leyın Bı ko ba pa ni A maa so ni di Afınju-afıja-gbuyı. (I�la 1-4)

Efunsetan Anıwura, I�yalode I�badan je akıkanju

obınrin tı ko sı ohun tı ko le �i enu re so. Enu re mu ju abe lo.

O� po ıgba ni o maa n �i ogun enu ba awon eru ati awon

enıyan tı o wa nı ayıka re ja. O� ro koba-kungbe ati alufansa

kun enu re fofo. Koda, elereke eebu ni a le pe e. E wo bı o ti

n ba awon eru re soro:

Efunsetan: Ha! Un un, un un,

E ko ı tı ı parı ise yıı lataaro Ha! E� yin omo ale wonyı Sıse koro, jıje ofe… Eni ıya, omo igi, omo eran niyın I�ya naa ni yoo je yın pa (o.i. 3)

A� �iwe I�yalode nınu ayolo oke yıı ko dara rara. O� �i enıyan

abemı we igi, eran ati ıya. A� won oro tı o wuwo tı o sı n ba

Page 14: Ipa Tí Ogun Ẹnu ń Kó Nínú Àwùjọysan.org/umgt/uploaded/184_Ipa_Ti_Ogun.pdf · 78 Ipa Tí Ogun Ẹnu ń Kó Nínú Àwùjọ ọ̀rọ̀ a máa bẹ tı́ kı̀ ı́ sáyè,

89

Yorùbá: Journal of the Yorùbá Studies Association of Nigeria (Vol. 9 No. 1)

okan je ni I�yalode lo fun awon eru re wonyı. O� rı won gege

bı alaınılaarı, eni tı ko wulo, tı ko jamo nnkankan ati eni tı

ıhuwası ati ısesı re buru jaı tı o sı jo ti eranko. A� won oro

wonyı dun awon eru wonyı wora. A� won nnkan wonyı ati

ıwa aıdara I�yalode sı awon eru wonyı lo fa a tı won �i pinu

lati fun un nı iwo je. Lara akoba ogun enu ni eyı. I�ja waye

laaarın I�tawuyı ati A� kano, won sı bere sı ı tahun sı ara won.

A� kano: A� won taa ni o n ba wı? Ha, egbin inu oko yıı ma tile po o Se emi ni ıwo fongbadı fongbadi ehın orun yıı n ba wı (o.i. 25)

I�tawuyı naa fesı pe:

E� mi? Se e n gbo omo abetı Kalasa bı awo I�lorin yıı? I�wo kinnı yıı (o.i. 25)

I�tawuyı ati A� kano �i enu ara won gbogun ti ara won. A� kıyesı

ırısı ara won ni o gbe eebu ara won jade (Adetoye,

2017:415).

A� won apeere ogun enu mııran tı o je mo oro lasan ni

eyı tı o n waye laaarın awon oloselu ati awon eleyameya.

I�wonyı ni won n se lati se atako ara won. Won a maa jagun

enu lorı redıo, ıwe ıroyın ati ero ayelujara. Bı won se n gba a

bı eni gba igba otı ni awon ara ılu yoo maa ba won da sı i. E

je kı a wo awon apeere wonyı:

Nı akoko ıdıbo Gomına A� mbode ti I�pınle E� ko, Oba Akiolu

pase fun gbogbo awon I�gbo tı n gbe nı I�pınle E� ko pe kı won

Page 15: Ipa Tí Ogun Ẹnu ń Kó Nínú Àwùjọysan.org/umgt/uploaded/184_Ipa_Ti_Ogun.pdf · 78 Ipa Tí Ogun Ẹnu ń Kó Nínú Àwùjọ ọ̀rọ̀ a máa bẹ tı́ kı̀ ı́ sáyè,

90

Ipa Tí Ogun Ẹnu ń Kó Nínú Àwùjọ

dıbo fun Gomına A� mbode laıbojuweyın. Sugbon ero yıı bı

awon I�gbo nınu pe ewo ni ti dandan kı won dıbo fun egbe

onıgbaale, All Progressives Congress (APC).

Oba Akıolu: I would not beg the Igbos in Lagos to cast their votes for the All Progressives Congress (APC) candidate… If you do what I want, Lagos will continue to be prosperous for you. If you go against my wish, you will perish in the water.

Igbo Stakeholders:

We will go back and convene a meeting of Igbo stakeholders and respond to him appropriately.

Oba Akiolu:

E� mi o nı ı be awon I�gbo to wa nı E� ko kı won dıbo fun oludıje egbe Onıgbaale (APC)… Tı e ba se ohun tı mo fe, E� ko yoo maa so eso rere fun yın. Tı e ba tako ıfe mi e o segbe sınu omi.

A� won Asoju I�gbo:

A maa pada lo pe ıpade awon asoju I�gbo a o sı fun un lesı bı o ti ye.

E gbo ohun tı Dokıta Junaid Mohammed so:

I don’t believe Buhari or Nigeria owe any Igbo anything. I don’t care what Ezeife says –

Page 16: Ipa Tí Ogun Ẹnu ń Kó Nínú Àwùjọysan.org/umgt/uploaded/184_Ipa_Ti_Ogun.pdf · 78 Ipa Tí Ogun Ẹnu ń Kó Nínú Àwùjọ ọ̀rọ̀ a máa bẹ tı́ kı̀ ı́ sáyè,

91

Yorùbá: Journal of the Yorùbá Studies Association of Nigeria (Vol. 9 No. 1)

If they (Igbo) had seceded, there would have been no Nigeria today. E� mi o gbagbo pe Buhari tabı Naıjırıa je I�gbo nı ohunkohun. N ko fe mo ohun tı Ezeife so. Tı o ba je pe awon I�gbo ti ya lo ni, Naıjırıa ıba ti parun.

Vanguard Newspaper, 12 October, 2014

Saaju 2014 ni Femi Fanı-Kayode ti se apejuwe awon eya

Igbo bayıı:

The Igbos are collectively unlettered, uncouth, uncultured, unrestrained and crude in all their ways… Money and the acquisition of wealth is their sole objective and purpose in life.

Daily Post, August 8, 2013.

O� pe ni awon I�gbo, won ko lekoo, won ko gbon, won sı nı ogbon alumokoroyı nı gbogbo ona… Owo ati ola ni ohun tı o mumu laya won tı won sı eredı ka sı ıwalaaye won.

Ohun tı Femi Fanı-Kayode n so ni pe owo ko ni gbogbo

nnkan laye. Bı enıyan ko lowo, tı o ba nıyı, ohun gbogbo lo

nı. Ogbon ni a �i n lo ile aye. A le ka olowo tı ko nı ogbon lılo

re sı olosı ponnbele. E� yı ni pe o rı awon I�gbo gege bı ıran tı

ko nı ogbon ısakoso bı ko se ogbon atilowo, kı won sı koro

jo.

Page 17: Ipa Tí Ogun Ẹnu ń Kó Nínú Àwùjọysan.org/umgt/uploaded/184_Ipa_Ti_Ogun.pdf · 78 Ipa Tí Ogun Ẹnu ń Kó Nínú Àwùjọ ọ̀rọ̀ a máa bẹ tı́ kı̀ ı́ sáyè,

92

Ipa Tí Ogun Ẹnu ń Kó Nínú Àwùjọ

O� gagun Muhammadu Buhari ni a gbo pe o so oro yıı nıgba tı

o n dıje fun ipo aare nı abe egbe oselu onıgbaale (APC) pelu

A� are Jonathan nı odun 2015. E gbo ohun tı o wı:

God willing, by 2015, something will happen. They either conduct a free and fair election or they go a very disgraceful way. If what happened in 2011 should again happen in 2015, by the grace of God, the dog and the baboon would all be soaked in blood.

Vanguard Newspaper, May 15th 2012.

Bı Oluwa ti fe nı odun 2015, nnkan yoo sele. A� ya�i kı won seto ıdıbo tı o duro ire tabı kı won lo pelu ıtıju. Bı ohun tı o sele nı 2011 ba sele nı 2015, nıpa oore ofe Olorun, ınakı ati aja yoo sun nı agbara eje.

Ohun tı o hande nınu apeere oke yıı ni wı pe oludıje tı o

soro yıı fe ri daju pe eto ıdıbo tı o duro ire waye. Nınu ohun

re, o dabı pe o mo pe bı ko ba ti sı eru nınu eto ıdıbo naa pe

o seese kı oun gbegba oroke. A lero pe o so oro yıı lati le je

kı tolorı telemu se ohun tı o to kı wahala ma baa sele. O� tun

hande nınu ohun re pe gbogbo ohun tı ıdıbo naa ba gba ni

oun yoo fun-un. O� ro tı o ko wa lominu ni ti awon ınakı ati

aja tı o lerı pe won yoo sun sınu agbara eje tı eto ıdıbo naa

ko ba duro ire. Se a wa le so pe oun tıkalare ati oludıje

akegbe re ni o nı lokan pe won yoo jo woya ıja ni tabı eya ti

gusu ati arıwa tı awon mejeejı ti wa ni o nı lokan ni tabı

awon oloselu ati awon mekunnu. A ko mo eyı tı o n toka sı

nınu won torı pe ko seni to mede ayan bı ko se eni to mopaa

Page 18: Ipa Tí Ogun Ẹnu ń Kó Nínú Àwùjọysan.org/umgt/uploaded/184_Ipa_Ti_Ogun.pdf · 78 Ipa Tí Ogun Ẹnu ń Kó Nínú Àwùjọ ọ̀rọ̀ a máa bẹ tı́ kı̀ ı́ sáyè,

93

Yorùbá: Journal of the Yorùbá Studies Association of Nigeria (Vol. 9 No. 1)

e lowo sugbon ohun tı o wa sı wa lokan ni pe ılerı pe ogun

yoo be sıle laaarın awon eya enıyan meji tı a ko mo pato ni

oludıje yıı nı lokan tı eto ıdıbo naa ko ba duro lorı otıto. E� yı

sı �ihan pe eni tı ko ra nıgba awon oloselu yoo san nıbe.

I�berubojo ati ıpaya ni o bo awon ara ılu nı akoko yıı latarı

oro tı o ti enu oludıje yıı jade.

E gbo ohun tı Alhaji Mujahid Dokubo-Asari so gege bı esı sı

oro oke yıı:

There will be no peace, not only in the Niger Delta, but everywhere if Goodluck Jonathan is not president by 2015, except God takes his life, which we do not pray for.

Vanguard Newspaper, May 5, 2013

Ko nıı sı alaafıa nıbi gbogbo tı Goodluck Jonathan ko ba di aare nı 2015, aya�i tı elemıın ba gba a, eyı tı a ko gbadura fun.

A� won oro kobakungbe wonyı ati opo mııran ni awon

oloselu �i n ba ara won ja tı won sı n ko ıpaya ba awon omo

orıle-ede yıı. Enu lolo yıı ni awon Hausa naa fohun tı won n

lerı furukoko wı pe tı awon Igbo ko ba kuro nı ılu won nı ojo

kınnı, osu kewaa odun 2017, pe eje yoo sun. Opelope

Olorun, adura ati awon eekan ılu ni ko je kı ılerı yıı se. Ogun

enu wonyı ko je kı awon ara ılu fedo lorı orooro.

Ogun E nu tí ó jẹ mo Èpè Ṣíṣe

A� peere ogun tı a tun le �i enu ja lawujo ni epe sıse. Rajı

(1987:10) toka sı epe gege bı ohun tı a ran sı enıkejı tabı so

Page 19: Ipa Tí Ogun Ẹnu ń Kó Nínú Àwùjọysan.org/umgt/uploaded/184_Ipa_Ti_Ogun.pdf · 78 Ipa Tí Ogun Ẹnu ń Kó Nínú Àwùjọ ọ̀rọ̀ a máa bẹ tı́ kı̀ ı́ sáyè,

94

Ipa Tí Ogun Ẹnu ń Kó Nínú Àwùjọ

jade tı sısele re ko ıbanuje tabı ıparun ba olodı eni. E� pe kı ı

se ohun tı o le se okunfa ıbagbepo alaafıa nı awujo. I�yalode

lo ıpede yıı nınu Ẹfúnṣetán ba awon eru re wı.

E fee maa jeun lasan ni, Sango ni yoo pa ıya yın lokookan. (o.i. 9)

A tun rı erı nınu oro ojogbon akewı kan to so bayıı pe:

…ıwo lo lo re e fowo agbana raja Lodo eni tı n rı se O� sı ti fepe ranse sıganna O� ti wo lule laırotı

O� pefeyıtımı (2010:21) so pe ko sı eyı tı o dara nınu epe

kekere ati nla. E� pe kekeke nıı di nla. Agbara gbıgbona sı wa

nınu epe. Bı ofo bı ayajo ni afo epe rı. Ohun odı ni epe, o sı le

fa ibi. Kı ı se ohun amusere rara bee ni kı ı se ohun

amuyangan. I�bınu ni o maa n fa epe sıse. Nıgba mııran,

awon alaımokan maa n �i epe sıse bara won sere laımo pe

ohun tı ko dara ni. Won a maa ro pe oro lasan ni, sugbon oro

loro, enu elomıran sı maa n nı ase. Orısıırısıı emı lo n gbe

inu afefe tı won sı n �i ase sı oro sıso. E� pe a maa fa orı

buruku ba enıyan, o sı le pani (Adetoye, 2009:22).

I�rırı ojukoroju laaarın awon orogun mejı nı odun dıe

seyın �i ıdı re mule pe epe sıse ko dara, kı enıyan sı maa so

enu re. I�ja waye laaarın awon orogun mejı yıı, won sı da epe

iku ojijı pada sı ara won laımo pe olugbohun wa nıtosı ile

won. O� se ni laaanu pe ile ojo naa ko su mo awon orogun

mejı yıı. Enu pa won, won kagbako ogun enu.

Page 20: Ipa Tí Ogun Ẹnu ń Kó Nínú Àwùjọysan.org/umgt/uploaded/184_Ipa_Ti_Ogun.pdf · 78 Ipa Tí Ogun Ẹnu ń Kó Nínú Àwùjọ ọ̀rọ̀ a máa bẹ tı́ kı̀ ı́ sáyè,

95

Yorùbá: Journal of the Yorùbá Studies Association of Nigeria (Vol. 9 No. 1)

Ogun Ẹnu tí ó jẹ mo Orin

O� nakona ni a le gba lo orin fun ohun tı a ba fe. Ko sı ıgba tı

Yoruba kı ı korin. Ohun ıdaraya patakı ni orin pelu. Orin wa

fun ıja ati ote bakan naa. Yoruba bo, won nı “ıja lode torin

dowe”. I�dı abajo lılo orin lati �i jagun enu ni wı pe yoo le wo

eni tı won ba korin bu lara. A� won gbolohun tı ko fani mora,

tı o kun fun efe, yeye ni o maa n ru ıbınu soke tı o sı le mu

eni sıwahu (Raji, 1987; ati Owolabı, 1987). Koda iru awon

orin yıı maa n pani lekun asunundake. E je kı a wo apeere

nınu awo orin Waheed A� rıyo tı o pe nı “Orogun O� wo”.

Mi ò wá sojà wá wòran (2x)

A� beke: E� yin le mohun to de tee �i namo Lımota Terın toyaya ni mo �i di Saarara E je tuju ka, ta lo nı o ma ta? Eni kan o se o, ma waya moya E posonu tı, kee dore wa (I�la 20-25)

I�dahun A� benı nıyı nınu awo orin kan naa:

A ti wa loja yıı ojo ti pe (2x) A� n ta, a n rere nıbe Alakorı woja, o di fıtına Oro la o �i pada �i le o lo

A� beke �i efe da orogun owo re lohun nı ılana epe bayıı:

Oluwa da ota mi lola Ola bıi koko Ola bıi eewo Ola bıi kuruna… Ola bıi tanmona

Page 21: Ipa Tí Ogun Ẹnu ń Kó Nínú Àwùjọysan.org/umgt/uploaded/184_Ipa_Ti_Ogun.pdf · 78 Ipa Tí Ogun Ẹnu ń Kó Nínú Àwùjọ ọ̀rọ̀ a máa bẹ tı́ kı̀ ı́ sáyè,

96

Ipa Tí Ogun Ẹnu ń Kó Nínú Àwùjọ

Nı akoko ıpolongo ıdıje sı ipo Gomına Dokıta Olusegun

Rahman A� bayomı Mimiko ati Olusegun A� gagu, orısıırısıı

orin ni awon omoleyın won �i n tako sıra won lati �i ara won

han gege bı akınkanju ati eni tı o ye fun ipo gomına saa naa.

Bı awon omo egbe Labour Party (LP) ba ti �i orin bonu

bayıı:

Gbogbo igi tı n be nıgbo I�roko ni baba igi I�jımere ni baba obo Olomosıkata baba agbado

Ni awon omo egbe People’s Democratic Party (PDP) naa yoo

maa gbe e pe

Gıge/Bıbe la o be o (2x) I�roko to gbabode Bıbe la o be.

I�roko ni oruko alaje fun Mimiko nıgba tı Power (Agbara) je

apeje fun egbe PDP. A� won LP n so pe awon ni baba, awon

PDP nı ko selegbe awon. Nı opo ıgba ni awon LP tun maa n

ju oko oro pelu orin yıı:

Alagbara ma mero baba ole A o gbodo gbo Power lenu yın mo.

I�wonyı ati awon ıpede mııran ni awon omo egbe �i n ba ara

won ja laılo ada ati oko tabı ıbon. Yato sı eyı, awon ile-ise

ıgbohun safefe maa n se amulo irufe awon ıpede yıı lojuna

lati �i han pe awon ni oga. E� yı ko �i danindanin yato sı orin ti

Page 22: Ipa Tí Ogun Ẹnu ń Kó Nínú Àwùjọysan.org/umgt/uploaded/184_Ipa_Ti_Ogun.pdf · 78 Ipa Tí Ogun Ẹnu ń Kó Nínú Àwùjọ ọ̀rọ̀ a máa bẹ tı́ kı̀ ı́ sáyè,

97

Yorùbá: Journal of the Yorùbá Studies Association of Nigeria (Vol. 9 No. 1)

awon orogun owo. Ile-ise ıgbohun safefe, A� daba 88.9 FM tı o

bale bage sı ılu A� kure maa n so bayıı pe:

A� daba gbera A� won yooku ti n sare ıje lo A� daba n bo leyın A� daba gbera O� sı ju gbogbo won lo

Suncity 101.9 FM nı ılu Ondo naa yoo wı pe:

A� wa ni baba won (2x) Adıye funfun lagba adıye Olomosıkata baba agbado A� wa ni baba won o E sa maa tele wa E sa maa tele wa o E� yın, eyın lomo adıye n toya re E sa maa tele wa o.

Owo ara eni ni a �i n tun ıwa eni se. Enu ni awon ile-

ise ıgbohunsafefe wonyı �i n jagun atajere nı ile-ise won.

Nınu ıwe ere-onıse Ẹfúnṣetán Aníwúrà ni orin ote ponbele

yıı ti jeyo gege bı Adetoye (2016:416) ti toka sı i. Adetutu,

okan lara awon eru I�yalode gboyun, inu I�yalode ko sı dun sı

eyı, bı I�yalode se n �i Adetutu se yeye ni o n ba a kedun lati �i

Adetutu han bı eni yepere tı ko ye kı o loyun. I�banuje gba

okan Adetutu, eru ba a, ile aye su u.

I�yalode: Yokolu Yokolu, ko ha tan bı?

I�yawo gboko sanle, oko yoke Yokolu Yokolu, ko ha tan bı? Onıyeye sebı oun le mu un je (eemeta) O� kuugbe torun bokun,

Page 23: Ipa Tí Ogun Ẹnu ń Kó Nínú Àwùjọysan.org/umgt/uploaded/184_Ipa_Ti_Ogun.pdf · 78 Ipa Tí Ogun Ẹnu ń Kó Nínú Àwùjọ ọ̀rọ̀ a máa bẹ tı́ kı̀ ı́ sáyè,

98

Ipa Tí Ogun Ẹnu ń Kó Nínú Àwùjọ

Nıbi Efunsetan de e sı Onıyeye sebı oun le mu un je… (o.i. 39-40)

I�yalode funra re loro nınu, o nıka nıkun. Ko derun bee ni ko

tura sıle rara. Ko loju aanu. O� ko lati yı ıwa buruku re pada.

O� su awon ara ılu. Nıgbeyın awon oloye ati awon ara ılu pa

ımo po lati rı eyın re. Lara ohun elo ıja tı won �i segun

I�yalode ni orin ote. Bı I�yalode ti gbo ıro orin yıı, ara re gbon,

eru ba a, jınnıjınnı bo o bı o ti fetı ko orin yıı pe:

Kı ı seru akata (eemeji) Kakata padıye Ko tun paladıye Kı ı seru akata… E bani soro naa ko ye wa Bıkun lo loko bı takute ni E bani soro naa ko ye wa (o.i. 171)

Orin yıı ati awon mııran ni won ko lati je kı sıbala sıbolo de

ba Efunsetan Anıwura.

Ogun Ẹnu tó jẹ mo Ewì Àwíṣẹ

Orısıırısıı ni awon ewı alohun Yoruba. Lara awon ohun ıjınle

enu Yoruba to lagbara ni Ofo, O� gede ati A� asan gege bı ese-

ifa se je ede awo tı a kı ı ku gırı lo. O� nı asıko ati ıdı tı a �i n lo

won. A maa n �i oro inu orıkı ati ofo da won mo. Atoyebı

(2012:1) ki ewı awıse gege bı:

A� kojopo oro tı a maa n so nı asosotunso pelu asayan oro tı a gbagbo pe won nı agbara lati je kı ero okan enıyan se, yala nı rere tabı nı ona mııran.

Page 24: Ipa Tí Ogun Ẹnu ń Kó Nínú Àwùjọysan.org/umgt/uploaded/184_Ipa_Ti_Ogun.pdf · 78 Ipa Tí Ogun Ẹnu ń Kó Nínú Àwùjọ ọ̀rọ̀ a máa bẹ tı́ kı̀ ı́ sáyè,

99

Yorùbá: Journal of the Yorùbá Studies Association of Nigeria (Vol. 9 No. 1)

Saaju Atoyebı (2012) ni awon onımo kan ti se ise lorı ewı

awıse. A� won bıi Bolorunduro (1979:2), Adenıyı (1982:ix),

Fabunmi (1982:vii), Olatunjı (1984:140), Rajı (1997:iv),

Rajı ati awon yooku (2000) ati bee bee lo. I�jınle oro to nı

agbara ati eto ni ewı awıse. Nınu Ayé Yẹ Won Tán ti I�sola

(2009:175), A� ronı ati awon yooku re ko fe kı oba bura nıdıı

ogun, won sı n sa gbogbo ipa won lati rı i pe ıbura naa ko se

e se. E je kı a wo ıtakuroso oun pelu A� yanlola.

A� ronı:

E� n soro ada, e n soro ıbon, ıbon a maa da ara re yın? A� da a maa da ara re gbe? Bı awa ba so fun aladaa pe kı o ko sıgbo, yoo ko sıgbo ni. Bı a ba so fun onıbon pe kı o maa gbon yoo maa gbon ni: Monamona kıı sıju weni tı o pa oun Teyınborun kıı sıju wOlodumare Barabara laa soro bara Sukusuku laa soro esuru Ebe tı kuluso ba ko laaaro E� yın re nı �i ı tu u ka

A� kıyesı inu ofo yıı ni pe yoo ra iye awon to n pe ofo le lorı ni.

I�mo won ko nıı jo mo. Ohun won yoo sı bere sı ı tako ara

won.

I�yalenu ni o je wı pe enıyan maa n beru ıbon, oko, obe

ati ada gan-an ni sugbon onıbon ati aladaa le di ode nıbi oro

ba ti bale, ko di ojo, kı ada ati oko ko lati sise. Bı apeere, bı

Page 25: Ipa Tí Ogun Ẹnu ń Kó Nínú Àwùjọysan.org/umgt/uploaded/184_Ipa_Ti_Ogun.pdf · 78 Ipa Tí Ogun Ẹnu ń Kó Nínú Àwùjọ ọ̀rọ̀ a máa bẹ tı́ kı̀ ı́ sáyè,

100

Ipa Tí Ogun Ẹnu ń Kó Nínú Àwùjọ

ole ba dani loju ona, tı o fe sani ladaa, tı oro ba jade tı ase sı

tele bayıı, a je pe ete ba ole naa nıyen.

A kı ı sa kıjo logbe A kı ı kun esu odara losun O� seewo Enıkan kı ı pa sokosobo saarın ılu Ile aye tı mo wa Ogbe ko nıı je temi Won o nıı sami pa N o nı saayan pa Bolobounboun ba jı A� nı aye oun di raunraun O� ya koro yın di raunraun.

A� kıyesı tı a fe mu jade nınu ofo mejeejı oke yıı ni wı pe, bı

awon kan ti le lo ogun ada, oko ati ıbon ni awon kan le lo

ogun enu. E� yı ni apeere ofo tı A� ronı pe ati ofo kejı n toka sı.

Eni tı a ba pe ofo aburu sı, ogun enu ni o ba onıtohun ja. Laı

lo ada, obe, oko ati awon ohun ıja ogun yooku, ise tı apofo

ba ran yoo dahun nı kıakıa, wahala yoo sı de ba onıtohun.

Àgbálọgbábo

A ti gbıyanju lati wo ohun tı a n pe nı ogun enu nınu ise yıı.

A salaye awon sakanı ibi tı ogun enu ti n jeyo. Bı awon

oloselu se n lo o ni awon orogun owo n lo o. A� won orogun

ise ati orogun ile naa n lo o lati gbena woju ara won.

Orısıırısıı ose ati ire tı o wa nınu ogun enu ni ise yıı tun

tepele mo. Ise yıı tun �ihan pe pupo nınu ogun abele, ogun

ılu, ogun orıle-ede, ogun agbaye ati ogun esın tı o n da

Page 26: Ipa Tí Ogun Ẹnu ń Kó Nínú Àwùjọysan.org/umgt/uploaded/184_Ipa_Ti_Ogun.pdf · 78 Ipa Tí Ogun Ẹnu ń Kó Nínú Àwùjọ ọ̀rọ̀ a máa bẹ tı́ kı̀ ı́ sáyè,

101

Yorùbá: Journal of the Yorùbá Studies Association of Nigeria (Vol. 9 No. 1)

gbogbo agbaye laamu nı akoko yıı ni ıpıle re je ogun enu. O�

sı tun han gbangba nınu ise yıı pe wahala tı a n koju lorıle-

ede Naıjırıa bayıı n waye latarı oro kobakungbe to n jade

lenu koowa wa ni. Pepa yıı fıdı re mule pe bı ire ti wa nınu

ibi naa ni ibi wa nınu ire. Ogun enu a maa seni nı suta, bee

ni o sı le gba ni lowo ewu. Bı o ti le buyı kun enıyan naa ni o

le so enıyan di olorıburuku. Nıtorı ıdı eyı, o ye kı a sora kı a

sı kıyesı oro enu wa.

Abenà Ìmo

Awo Awogbola Adesegha, No. 8, Ajibeye Street, Ondo State –

18/09/2017

Ìwé Ìtokasí

Abimbola, W. (1968). I�jınle Ohun Enu Ifa: Apa Kıını. Glasgow: WM, Collins, Sons and Co. Ltd.

Adenıyı, D.A.A. (1982). Àwọn Ìjìnle Ohùn Ife. I�badan: Onıbonoje Press.

Adetoye, A. O. (2016:412-419). “Ipa ati Ipo Ogun Enu Nınu I�we Ere-Onıtan Efunsetan Anıwura” nınu Rajı, S.M.; Fajenyo, R.; Aderıbigbe, M.M.; Adesuyan, R.A. ati O� jo, I.F. (A� won Olootu) Èdè, Àṣà àti Lítíréṣo Yorùbá: Ìtàn-ò-ní-gbàgbé yín. I�badan: Masterprint Publishers.

Adetoye, A.O. (2009). I�mo I�jınle E� ro Yoruba Lorı Ogun Enu. Master of Arts Thesis, University of Ilorin.

Agboola, A.F. (1989). Ojúlówó Oríkì Ifá. Lagos: Project Publication Limited.

Page 27: Ipa Tí Ogun Ẹnu ń Kó Nínú Àwùjọysan.org/umgt/uploaded/184_Ipa_Ti_Ogun.pdf · 78 Ipa Tí Ogun Ẹnu ń Kó Nínú Àwùjọ ọ̀rọ̀ a máa bẹ tı́ kı̀ ı́ sáyè,

102

Ipa Tí Ogun Ẹnu ń Kó Nínú Àwùjọ

Akıwowo, A. (2003). “War Ethics Among the Yoruba” nınu Adeagbo Akınjogbın (ed.) War and Peace in Yorubaland 1973-1893. I�badan: Heinemann Educational Books (Nigeria) Plc.

Asaolu, Y. (1981). Ìwé Ìléwo Ifá Yorùbá Fún Àwọn Akekoo. Ilesa: Fatıregun Press and Publishing Co. (Nig) Ltd.

Atoyebı, J.A. (2012). Ewì Àwíṣẹ. I�lorin: Haytee Press and Publishing Company.

Bada, S. (1970). Òwe Yorùbá àti Ìṣedále Wọn. I�badan: Oxford University Press.

Bolorunduro, K. (1979). Àgbéyewò Ọfo àti Ògèdè. Ilesa: Fatıregun Press and Publishing Company.

Daily Post, August 8, 2013.

Epega, D.O. (1924). Ifá Amonà àwọn Baba Wa. I�badan: Oxford University Press.

Fabunmi, M.A. (1972). Àyájo: Ìjìnle Ohùn Ife. I�badan: Onibonoje Press.

Holy Bible (2009). King James Version

I�sola, A. (1970). Ẹfúnṣetán Aníwúrà. I�badan: University Press.

I�sola, A. (2009). Ẹfúnróyè Tinúbú. I�badan: DB Martoy Books.

O� gunyemı, R.A. (1998). Ìtọpinpin Lítíréṣo Yorùbá. Ondo: Noveclor Printers.

Olatunjı, O.O. (1984). Features of Yorùbá Oral Poetry. I�badan: University Press Ltd.

O� pefeyıtımı, R.A. (2010). Ìtúpale Èpè. Ile-Ife: OAU Press.

Page 28: Ipa Tí Ogun Ẹnu ń Kó Nínú Àwùjọysan.org/umgt/uploaded/184_Ipa_Ti_Ogun.pdf · 78 Ipa Tí Ogun Ẹnu ń Kó Nínú Àwùjọ ọ̀rọ̀ a máa bẹ tı́ kı̀ ı́ sáyè,

103

Yorùbá: Journal of the Yorùbá Studies Association of Nigeria (Vol. 9 No. 1)

Rajı, S.M. (1987). Ìjìnle, Ọfo, Ògèdè àti Àásán. I�badan: University Press Limited.

Rajı, S.M., I.F. O� jo, J.B. Fatoba, J.B. Olorunmowaju, ati E.O. Akınwale (2009). Ewì Àwíṣẹ Yorùbá: Àyájo 1. I�badan: Alafas Nigeria Company.

Rajı, S.M., I.F. O� jo, J.O. Fatoba, S.A. A� juwon ati M.A. Fasehun (2009). Ewì Àwíṣẹ Yorùbá: Ọfo. I�badan: Alafas Nigeria Company.

Vanguard Newspaper, August 12, 2014.

Vanguard Newspaper, May 15th, 2012.

Vanguard Newspaper, May 15th, 2013.