Ipa Pàtàkì tí Orín ń Kó Nínú Ètò Ogun Jíjà Nílẹ̀...

26
Ipa Pàtàkì tí Orín ń Kó Nínú Ètò Ogun Jíjà Nílẹ̀ Yorùbá Ọ wọ́ adé Sunday Caleb Department of Linguistics, African and Asian Studies University of Lagos, Akoka, Lagos State [email protected] Àṣamò ̣ A kò lè ṣòdiwò ̣n ipa pàtàkì tí orín máa ń kó nínú ètò ogun jíjá láwùjọ ẹ̀dá káríayé, pàápàá jùlọ, láwùjọ Yorùbá. Yorùbá ní orin níí ṣaájú ò ̣ tẹ̀, bí ọwó ̣ gẹngẹ ṣe ń ṣíwájú ijó. Ó sì hàn pé ò ̣ tẹ̀ níí dogun daáwò ̣, tíí fa yánpọnyánrin, sò ̣ lú dahoro. Orin náà níí mú kóríyà bá àwọn ọmọ ogun lójú ogun. Ìdí nìyí tí a kò i lè kóyán orin kéré nínú ètò ogun jíjà láwùjọ Yorùbá. Lára àwọn orin ò ̣hún ni orin òwe, ìmò ̣ràn, àṣamò ̣ , ò ̣ tẹ̀, ìfẹ̀hónúhàn, ìṣìpẹ̀, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ọ pò ̣ onímò ̣ lítíréṣò ̣ Yorùbá ló ti ṣiṣẹ́ lórí ewì alohùn nínú àṣà ilẹ̀ Yorùbá ló ̣nà kan tàbí òmíràn. Wó ̣n sì gbìyànjú láti ṣàihàn ipa pàtàkì tí wọ́n ń kó nínú àṣà àwùjọ Yorùbá tí ò ̣ kò ̣ ò ̣kan wọn ti jẹyọ. Àmó ̣, wọn kò fúnka mó ̣ ipa pàtàkì tí orin ń kó nínú ètò ogun jíjá láwùjọ Yorùbá. Èyí ló fà á tí pébà yìí i ṣe àgbéyẹ̀wò ipa pàtàkì tí orin máa ń kó nígbà ogun jíjà ní àwùjọ Yorùbá. Tíó ̣rì Ìfojú-ìmò ̣-ìbára-ẹni-gbé-pò ̣ ti lítíréṣò ̣ (Soṣíó ̣ ló ̣jì lítíréṣò ̣) tí ó tó ̣ka sí ìbáṣepò ̣ tó wà láàárín iṣẹ́-ọnà, oníṣẹ́ ọnà àti àwùjọ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ta-òkò ni a lò láti ṣe ìtúpalẹ̀ iṣẹ́ yìí. Ìwádìí yìí ṣàihàn iṣẹ́ pàtàkì tí ò ̣ kan nínú àwọn

Transcript of Ipa Pàtàkì tí Orín ń Kó Nínú Ètò Ogun Jíjà Nílẹ̀...

Page 1: Ipa Pàtàkì tí Orín ń Kó Nínú Ètò Ogun Jíjà Nílẹ̀ Yorùbáysan.org/umgt/uploaded/186_Ipa_Pataki.pdf · 2018-10-08 · Ipa Pàtàkì tí Orín ń Kó Nínú Ètò Ogun

Ipa Pàtàkì tí Orín ń Kó Nínú Ètò Ogun Jíjà Níle Yorùbá

O� woadé Sunday Caleb

Department of Linguistics, African and Asian Studies University of Lagos, Akoka, Lagos State

[email protected]

Àṣamo

A kò lè ṣòdiwon ipa pàtàkì tí orín máa ń kó nínú ètò ogun jíjá

láwùjọ edá káríayé, pàápàá jùlọ, láwùjọ Yorùbá. Yorùbá ní

orin níí ṣaájú ote, bí ọwo gẹngẹ ṣe ń ṣíwájú ijó. Ó sì hàn pé ote

níí dogun daáwo, tíí fa yánpọnyánrin, solú dahoro. Orin náà

níí mú kóríyà bá àwọn ọmọ ogun lójú ogun. Ìdí nìyí tí a kò �i

lè kóyán orin kéré nínú ètò ogun jíjà láwùjọ Yorùbá. Lára

àwọn orin ohún ni orin òwe, ìmoràn, àṣamo, ote, ìfehónúhàn,

ìṣìpe, àti bee bee lọ. O� po onímo lítíréṣo Yorùbá ló ti ṣiṣe lórí

ewì alohùn nínú àṣà ile Yorùbá lonà kan tàbí òmíràn. Won sì

gbìyànjú láti ṣà�ihàn ipa pàtàkì tí won ń kó nínú àṣà àwùjọ

Yorùbá tí okookan wọn ti jẹyọ. Àmo, wọn kò fúnka mo ipa

pàtàkì tí orin ń kó nínú ètò ogun jíjá láwùjọ Yorùbá. Èyí ló fà

á tí pébà yìí �i ṣe àgbéyewò ipa pàtàkì tí orin máa ń kó nígbà

ogun jíjà ní àwùjọ Yorùbá. Tíorì Ìfojú-ìmo-ìbára-ẹni-gbé-po ti

lítíréṣo (Soṣíolojì lítíréṣo) tí ó toka sí ìbáṣepo tó wà láàárín

iṣe-ọnà, oníṣe ọnà àti àwùjọ gege bí eta-òkò ni a lò láti ṣe

ìtúpale iṣe yìí. Ìwádìí yìí ṣà�ihàn iṣe pàtàkì tí okan nínú àwọn

Page 2: Ipa Pàtàkì tí Orín ń Kó Nínú Ètò Ogun Jíjà Nílẹ̀ Yorùbáysan.org/umgt/uploaded/186_Ipa_Pataki.pdf · 2018-10-08 · Ipa Pàtàkì tí Orín ń Kó Nínú Ètò Ogun

132

Ipa Pàtàkì tí Orín ń Kó Nínú Ètò Ogun Jíjà Níle Yorùbá

ewì alohùn ń ṣe nínú ètò ogun jíjà ní àwùjọ Yorùbá, yálà ní

pípetù sááwo, ṣise kóríyá fún áwọn ọmọ ogun, ríru- ote sókè,

ìfehónúhàn, gbígbani nímoràn, ìpàṣamo àti bee bee lọ. Ó hàn

ní ìkádìí ìwádìí yìí pé àwọn okọrin pelú àwọn ará ìlú kò kàn

máa pèdè ajẹmo-ogun lásìkò ogun láwùjọ Yorùbá lásán, bí kò

ṣe pé láti je kí omi àwùjọ tòrò, kí ó sì dùn-ún gbé fún tẹrú-

tọmọ.

Kókó oro: Orin, ewı alohun, ogun jıja, Sosıolojı lıtıreso, awujo Yoruba.

Ìfáárà

Bı ıgbın fa, ıkarahun a tele e loro orin ati ogun jıja je lawujo

Yoruba, ati lawujo eya gbogbo karı-aye. A sı tun le so pe

Gege leyın Apena ni orın je sı ogun jıja nıle Yoruba. Bı a ba

so pe orin laya, ote loko, ogun sı je omo tı won bı, a o jayo

pa. A� won orin tı a se agbeyewo won ni awon orin tı awon

jagunjagun tabı ara ılu ko nıgba awon ogun bı ogun I�jaye

(1860-1865), ogun I�peru, ogun Gbanamu (1830), ogun

A� dubı (1914-1918) ati ogun A� gbekoya (1968-1970) ati

awon orin mııran tı o je mo akorı ise yıı. A tun �i oro wa

awon agba to nımo nıpa awon ogun to waye nıle Yoruba

lenu wo. Ni bi tı a tı rı awon orin ajemo ogun gba. A� won orin

tı a rı gba nı oko ıwadıı naa nı a sı gbe yewo nınu ise yıı.

A� won Yoruba feran orin pupo lawujo won. I�dı nıyı tı

ko �i sı ohun tı o n sele nı awujo won tı won ko le korin nıpa

re. I�ran Yoruba nıfee lati maa �i orin gbe ohun to je won

Page 3: Ipa Pàtàkì tí Orín ń Kó Nínú Ètò Ogun Jíjà Nílẹ̀ Yorùbáysan.org/umgt/uploaded/186_Ipa_Pataki.pdf · 2018-10-08 · Ipa Pàtàkì tí Orín ń Kó Nínú Ètò Ogun

133

Yorùbá: Journal of the Yorùbá Studies Association of Nigeria (Vol. 9 No. 1)

logun jade, yala eyı to je mo ıdunnu tabı eyı to je mo ıbanuje

(Fajenyo, 2016:157). Awolalu ati Dopamu (1979) nınu

Ajıkobi (2000:ix) so pe:

In all, songs tell stories of the people’s past…they also express the joy and sorrows of the people, their assurances, hopes and fears of the future and life after death. Ju gbogbo re lo, orın maa n sa�ihan ıtan awon enıyan to ti koja…won sı maa n sa�ihan ayo ati ıbanuje awon enıyan naa, ıdaniloju won, ıretı ati eru nıpa ojo-ola ati aye leyın iku.

Bı oro orin se rı gele lawujo Yoruba ni awon onımo yıı so.

Koda, won je kı a mo ipa patakı tı orin n ko nı ıgbe aye eda,

paapaa laye awon omo Yoruba. Ise patakı tı Awolalu ati

Dopamu nı orin n se lawujo eda yıı ba ipa patakı tı awon

orin tı a ko jo fun agbeyewo ko laye awujo Yoruba to ko won

nıgba ogun tı won ti ko won. Lakooko, gbogbo awon orin tı

a lo mu gbogbo ısele to bı won wa sı ırantı ati etı-ıgbo awon

omo Yoruba. Yoruba bo, won nı ‘bı omo o ba ba ıtan, a ba

aroba; aroba sı nıyı, baba ıtan ni o je’.

Agbaje nınu Fajenyo (2016:157-158) nı ‘orin nı

agbara nı ile Yoruba debi pe o le muni sıwa hu tabı ko yıni

lokan pada sı rere’. O� tıto ni ero onımo yıı, o sı je arıdaju

nıtorı pe o han nınu awon orin ajemogun tı a gbeyewo pe

opolopo ogun to sele nıle Yoruba lo je pe orin ote lo bı won,

ati pe orin naa nıı sabaa n fopin sı ogun to maa n waye

Page 4: Ipa Pàtàkì tí Orín ń Kó Nínú Ètò Ogun Jíjà Nílẹ̀ Yorùbáysan.org/umgt/uploaded/186_Ipa_Pataki.pdf · 2018-10-08 · Ipa Pàtàkì tí Orín ń Kó Nínú Ètò Ogun

134

Ipa Pàtàkì tí Orín ń Kó Nínú Ètò Ogun Jíjà Níle Yorùbá

lawujo Yoruba. E� yı tumo sı pe irinse koseemanıı patakı ni

orin je nınu eto ogun-jıja nı ile Yoruba.

Nı tire, Adebajo (2016:247) je kı a mo ohun tı orin je,

patakı re ati ıwulo re lawujo Yoruba nıgba tı o so pe:

Ewı lorin, orin lewı. Koseemanıı lo je fun ıran asuwada. O� na to patakı lati gbe ero okan wa jade ni orin kıko. A �i n waasu, a �i n kılo ıwa, a n korin lati fa ıjangbon lese, a n �i orin tu ıbaje okan ka, a n korin lati mu ise ya…

Adu ati Aderıbigbe (2016:402) nı ‘orin dabı ılu oloju mejı,

gege bı o se wulo fun eni to n ko o naa lo sanfanı fun eni to n

gbo o nıtorı a maa n �i orin paroko’. A le so pe orin je okun

emı awujokawujo tı eda enıyan n gbe.

Ipa patakı ni ogun jıja ko nınu ıtankale ıran Yoruba.

E� yı ni ko je kı ogun jıja je ajojı sı awon eya Yoruba lati aaro

ojo wa. A� sa ogun jıja yıı lo tete sa�ihan eya Yoruba karıaye

gege bı eya aaro ati eya to feran ogun jıja. Yoruba bo, won

nı: Ohun mejı laa ba rogun: ekını, n o meru; ekejı, n o pa ota,

sugbon bı a ba de oju ogun tan, eketa a maa bani, won a sı

mu oluwa re leru. O� we yıı �i ohun tı ogun jıja je lawujo han

pe ko sı eni to le mo opin ogun jıja lati ıbere. Loooto ni pe ko

sı jagunjagun tı yoo gbadura pe kı ogun ko oun, amo opo

ıgba ni igi tı eda ba foju rena maa n gun un loju, tı a sı tun se

mo on loju pelu.

O� polopo awon onımo lo ti sise lorı ogun jıja lawujo

eda, paapaa lawujo Yoruba. Won ko saıso ohun tı ogun jıja

je, bı ogun se maa n sele ati bı eto ogun jıja se maa n waye.

Page 5: Ipa Pàtàkì tí Orín ń Kó Nínú Ètò Ogun Jíjà Nílẹ̀ Yorùbáysan.org/umgt/uploaded/186_Ipa_Pataki.pdf · 2018-10-08 · Ipa Pàtàkì tí Orín ń Kó Nínú Ètò Ogun

135

Yorùbá: Journal of the Yorùbá Studies Association of Nigeria (Vol. 9 No. 1)

Koda, won yannana awon ohun tı o maa n fa ogun jıja laarin

awon ılu mejı tabı ju bee lo nıle Yoruba ati karıaye. Orısirısi

ogun tı awon Yoruba ja lawujo won ati ıgba tı won ja won ko

farasin nınu ise awon onımo naa. Lara awon onımo ohun ni

Johnson (1921), Oyerınde (1934), Abraham (1958), A� jayı

ati Smith (1971), Adeoye (2005) ati Oyelade (2011). Nınu

ise awon onımo wonyı, o han pe ısetopinpin ogun jıja nıle

Yoruba ko le see se laı�i ti ıtan ati ti ıselu awujo Yoruba mo

on. E� yı lo mu Awe (1975:267) so bayıı:

Any attempt to understand the history of the Yoruba must therefore include a detailed study of their warfare: for war is a manifestation of the break-down of normal political relationship. I�gbıyanjukıgbıyanju lati nı oye nıpa ıtan awon Yoruba nı lati se ekunrere alaye nıpa eto ogun jıja won: nıtorı pe ogun nı abajade ıdojuru eto ıselu won.

Nı ero ti Adeoye (2005), mejı ni ogun tı o le koju eda

laye. O� nı akoko ni ogun adaja, tı ekejı sı je ogun ajakuakata.

Ogun adaja ni o pe nı awon wahala tı o maa n doju ko enı

kookan bı arun, aısan, ati awon ıdanwo lorısirısi. A� mo ogun

ajakuakata ni eyı tıı kan ara-ile kan ara oko. Koda a maa de

ba ‘jeje mi ni mo jokoo’. Adeoye (2005:295) nı “Kı iru ogun

bayıı to bere, orin nıı koko saaju owe, ote nıı sı ı saaju ıja’’.

Orısirısi ohun ni o le fa ogun jıja lawujo eda karıaye. Yoruba

bo, won nı ‘ese kan kı ı sadeede se’. Lara awon nnkan tı

Page 6: Ipa Pàtàkì tí Orín ń Kó Nínú Ètò Ogun Jíjà Nílẹ̀ Yorùbáysan.org/umgt/uploaded/186_Ipa_Pataki.pdf · 2018-10-08 · Ipa Pàtàkì tí Orín ń Kó Nínú Ètò Ogun

136

Ipa Pàtàkì tí Orín ń Kó Nínú Ètò Ogun Jíjà Níle Yorùbá

awon Yoruba ati awon onımo nıpa ogun jıja nı o maa n fa

ogun jıja lawujo eda enıyan, laıyo ile Yoruba sıle, ni emı ılara

ati ıreje, aala ile, sunmomı gbıgbe, gbıgbese le ohun-ını

elomıran, fıfe �i alagbara han laarin awon ılu tabı eya mejı,

ati bee bee lo. I�sorı kejı yıı sı ni o kan wa nınu ise yıı lati se

agbeyewo awon ise patakı tı awon Yoruba maa n forin se

nıgba tı ogun ajakuakata yıı ba sele nıle won.

Tíorì Soṣíolojì Lítíréṣo

Tıorı je ohun-elo tabı irinse ti asewadıı maa n lo lati se

agbeyewo tabı ıtupale ise-ona. Adeyemı (2006:8) nı ‘Tıorı

dabı abefele ımo tı a �i n la ıfun ati edo ise kan’. Orısirısi ni

awon tıorı tı o wa tı a le lo lati se ıtupale ise ona lıtıreso. Ko

sı sı asadanu nınu gbogbo awon tıorı ohun. Sugbon fun

patakı ise yıı, tıorı ımo ıbara-eni-gbe-po ti lıtıreso ni a yan

laayo. I�dı ni pe a gba pe o kunju ıwon lati so okodoro oro to

wa laarin ise-ona, onıse ona ati awujo.

O� polopo awon onımo lıtıreso ni won ti sise lorı tıorı yıı, tı

won sı fıdı re mule pe eso awujo ni lıtıreso je. O� sı han pe

Hippolyte Taine tı ı se omo ile Faranse ni o se agbateru tıorı

yıı kı o le rorun fun awon lameeto lati mo ıbasepo ko-legbe

tı o wa laarin ise-ona (lıtıreso), onıse ona (akewı tabı

onkowe) ati awujo to bı awon mejeejı. O� ye eyı han nınu ise

awon onımo lıtıreso bı O� pefeyıtımı (1997), Adeyemı

(2005), Faturotı (2010) ati I�lorı (2017). I�lorı (2017:162) nı:

O� ye kı a �i ote le e pe awujo lo bı lıtıreso. E� so awujo ni, orı ısele to ba sele lawujo ni lıtıreso

Page 7: Ipa Pàtàkì tí Orín ń Kó Nínú Ètò Ogun Jíjà Nílẹ̀ Yorùbáysan.org/umgt/uploaded/186_Ipa_Pataki.pdf · 2018-10-08 · Ipa Pàtàkì tí Orín ń Kó Nínú Ètò Ogun

137

Yorùbá: Journal of the Yorùbá Studies Association of Nigeria (Vol. 9 No. 1)

n da le. Inu awujo ni gbogbo ise ona ti se, tı won sı n gbile si. Lıtıreso yowu ko je orı ısele awujo lo da le lorı, yala awujo enıyan, eranko tabı awon eda abamı.

E� ro yıı wa nı ıbamu pelu orin tı o je afojusun wa nınu ise yıı

tı ı se ise-ona lıtıreso tı o je eka kan nınu ewı alohun.

A� wujo lo bı orin ajemogun wonyı, eso awujo Yoruba

ni pelu; bee ni orı ısele to se lawujo Yoruba nıgba tı won n

jagun tabı bara won sote ni awon orin naa da le. A� wujo

Yoruba sı ni gbogbo ogun jıja naa ti sele. E� yı tumo sı pe a ko

le ya awon eta-oko wonyı kuro lara won, nıtorı pe ısele

awujo lo bı ero okan okorin nı iru awujo yowu tı okorin bee

ba ba ara re. Inu awujo ni okorin/akewı ti wa, o �i orin tı o

ko paroko awon ısele awujo sı awon olugbo re. E� yı �i han pe

awon enıyan to wa nı awujo re ni o ko orin ohun fun lati mo

ohun to n sele lowolowo, tabı eyı to ti sele tele ati lati je kı

awon enıyan mo nıpa ohun to see se kı o sele lojo iwaju. O� sı

tun �i ero re han nıpa awon akıyesı tı o se nıpa awon ısele

naa.

Sosıolojı lıtıreso �i han pe dıngı tı a �i n wo awujo eda

ni lıtıreso je. Laurenson ati Swingwood (1971) nınu I�lorı

(2017:163) �i han pe Lious De Bonald (1754 – 1840) lo so

oju abe nıkoo pe dıngı awujo ni lıtıreso je nınu ohun tı o pe

nı ‘’Mirror Image Approach’’. David Bleich (1976:7) je kı a

mo pe:

Page 8: Ipa Pàtàkì tí Orín ń Kó Nínú Ètò Ogun Jíjà Nílẹ̀ Yorùbáysan.org/umgt/uploaded/186_Ipa_Pataki.pdf · 2018-10-08 · Ipa Pàtàkì tí Orín ń Kó Nínú Ètò Ogun

138

Ipa Pàtàkì tí Orín ń Kó Nínú Ètò Ogun Jíjà Níle Yorùbá

Literature is a reflection of people, and in it we can see human problems and concerns that we are going through ourselves. Lıtıreso je awojiıji enıyan, nınu re ni a ti le rı ısoro awa eda ati awon nnkan to kan wa gbongbon tı awa tıkara wa n la koja.

A� won agbateru tıorı yıı gbagbo pe asewadıı gbodo rı i daju

pe koko-oro ise-ona lıtıreso ba ısele to n sele lojoojumo mu.

Bı a ba wo awon orin ajemogun tı a gbe yewo nıbı, a o rı i pe

won toka sı awon ısele tı o se lawujo Yoruba nı awon akoko

kan tı won sı n gbe awon koko-oro to je awon to korin naa

nıgba naa jade kı tonıle-talejo le mo ohun tı o je won logun,

ati pe iru akıyesı tı won se nıpa awon ısele awujo naa.

Ohun tı o je wa logun nınu ise yıı ni alaye tı

Laurenson ati Swingwood (1971:107) se pe o rorun fun

onımo lıtıreso tı o se amulo tıorı Sosıolojı Lıtıreso lati rı

onıse ona (bı apeere okorin/akewı) gege bı eni to n so bı

awujo se rı nı akoko kan nıpase ise-ona (orin nı patakı) to �i

n ta awujo jı. Nı ıbamu pelu alaye oke yıı, a o wo ise tı awon

to korin ajemogun n �i orin wonyı je lawujo Yoruba. Iru ise

tı won �i je tabı aroko tı won �i pa pelu ıdı tı won �i lo won

nıgba naa yoo hande nınu ıtupale wa. E� yı yoo sı so ipa

patakı tı awon orin naa ko nı awujo awon to lo won nıle

Yoruba nıgba naa.

O� kookan awon orin tı a yan fun atupale yıı ni yoo so

koko ise tı awon to korin wonyı n se lawujo Yoruba, ati

Page 9: Ipa Pàtàkì tí Orín ń Kó Nínú Ètò Ogun Jíjà Nílẹ̀ Yorùbáysan.org/umgt/uploaded/186_Ipa_Pataki.pdf · 2018-10-08 · Ipa Pàtàkì tí Orín ń Kó Nínú Ètò Ogun

139

Yorùbá: Journal of the Yorùbá Studies Association of Nigeria (Vol. 9 No. 1)

ıbasepo to wa laarin awon olugbe awujo naa nıgba naa ati

awon ısele tı o se okunfa kıko awon orin ohun. I�gba ati asıko

tı won ko awon orin naa ko nı gbeyın nınu alaye wa gege bı

o se han nınu agbekale awon orin naa.

Ìgbà tí àwọn Orin Ajẹmógun máa ń wáyé nínú Ètò Ogun

Jíjà níle Yorùbá

Bı ohun gbogbo se wa nı eto nı eto nı awujo Yoruba, naa ni

awon Yoruba maa n lo awon orin ajemogun nıgba tı o ye.

Won kı ı nase kı won to jokoo, bee ni won kı ı kan maa korin

ajemogun nıgba to ba wu won, bı ko se nıgba to ba ye.

Yoruba kı ı gbomo Oba fun O� sun rara. O� na meta ni a le pın

ıgba tı awon orin ajemogun maa n waye tabı tı awon Yoruba

maa n korin ajemogun nınu eto ogun jıja nıle won sı. A� won

ıgba naa ni:

a. kı ogun jıja to bere tabı nı ıbere ogun jıja

b. nıgba tı ogun jıja n lo lowo

d. nıgba tı ogun jıja ba parı

Orin ajẹmógun ṣáájú ogun jíjà tàbí ní ìbere ogun jíjà

A� won Yoruba maa n ko awon orin ajemogun wonyı, yala kı

ogun jıja to bere tabı nı ıbere ogun jıja. Nı opo ıgba, awon

orin wonyı lo maa n da rugudu sıle togun jıja �i maa n waye

laarin ılu mejı tabı ju bee lo. O� sı le je eyı tı ılu kan �i pe

omıran nıja. Yoruba le lo orin wonyı saaju ogun tabı nı ıbere

ogun jıja lati mu orı awon omo ogun ya ati lati kı won laya.

Page 10: Ipa Pàtàkì tí Orín ń Kó Nínú Ètò Ogun Jíjà Nílẹ̀ Yorùbáysan.org/umgt/uploaded/186_Ipa_Pataki.pdf · 2018-10-08 · Ipa Pàtàkì tí Orín ń Kó Nínú Ètò Ogun

140

Ipa Pàtàkì tí Orín ń Kó Nínú Ètò Ogun Jíjà Níle Yorùbá

A� peere irufe orin bee ni eyı tı awon omo Yoruba maa n ko nı

ıgba ti won ba n lo sı oju ogun. Okan nınu awon orin naa

nıyı:

I�pade doju ala I�pade doju ala Bıkun lo loko ni, Bı takute ni. I�pade doju ala.

A� won omo ogun le ko orin yıı pade awon ota won. Orin naa

n �i han pe awon omo to n ko orin yıı nıı lokan pe awon n lo

�i agba han awon ota won nı oju ogun ni.

O� mıra ni eyı tı O� gunmola ti ile I�badan nı kı awon onılu re ati

awon onılu awon ıjoye re ko lati �i han pe oun ti setan lati ko

ogun ja awon I�jaye. Orin naa nıyı:

A� foke, A� �i’gbo, Ko seni tı o le duro. Johnson (1921: 423)

Orin yıı ko ıpaya ati jınnınjınnın ba awon I�jaye nıgba tı won

gbo o. Inu won sı baje pe I�badan tun gbe ogun kawon mole.

O� mıran ni orin tı awon I�seyın ko lati fero okan won

han pe awon o beru I�badan rara, pe tı won o ba towo omo

won boso, awon a doju ogun ko I�badan. I�seyın ko sadeede

korin naa, bı ko se ıwa ıfowo-ola gbani loju tı a gbo pe awon

omo I�badan kan n hu sı won. Orin tı won ko naa nıyı:

I�badan tı o ko, Tı ko lo. Awowo a wo o. (ibid:421)

Page 11: Ipa Pàtàkì tí Orín ń Kó Nínú Ètò Ogun Jíjà Nílẹ̀ Yorùbáysan.org/umgt/uploaded/186_Ipa_Pataki.pdf · 2018-10-08 · Ipa Pàtàkì tí Orín ń Kó Nínú Ètò Ogun

141

Yorùbá: Journal of the Yorùbá Studies Association of Nigeria (Vol. 9 No. 1)

O� jelabı ni omo I�badan tı won le tı ko lo. Dıpo ko kuro nı

I�seyın, nı ı se lo tun n dana sun ile awon I�seyın. E� yı mu kı

awon I�seyın fokuta le e jade kuro nı I�seyın laıko ohun to le

da laarin awon ati I�badan. A� mo, I�badan pelu ko dake rara,

awon naa forin da I�seyın lohun pe:

A fadamo da’mo lekun Awowo.

Orin ajẹmógun nígbà tí ogun jíjà ń lọ lowo

Orin wonyı ni awon Yoruba maa n ko loju ogun, yala lati �i

se ıkılo fun awon omo ogun tabı ara ılu, tabı tı won maa n lo

lati mu awon omo ogun lokan le, ati lati se korıya fun awon

jagunjagun kı won le jajaye. Dıe lara awon orin naa ni

wonyı:

I�bıkunle, A o se won, A o se won, Egba ko mo ogun jıja, A o se won. Johnson (1921:414)

O� gunmola lo korin yıı nıgba to sabewo sı awon omo ogun

I�badan tı Balogun I�bıkunle je olorı fun nı asıko tı ogun I�jaye

n lo lowo laarin I�badan, I�jaye ati E� gba. O� korin naa lati je kı

Balogun I�bıkunle mo pe awon omo ogun E� gba ko mo bı o ti

ye kı won ja ogun naa lajaye. O� ke lala ni awon jagunjagun

E� gba n yınbon sı, nıtorı pe won ko fıgba kan ko bı a tı jagun

bıi ti awon I�badan. A� jayı ati Smith (1971:29) tile kın eyı

leyın nıgba tı won so pe “The Yoruba wars were fought with

Page 12: Ipa Pàtàkì tí Orín ń Kó Nínú Ètò Ogun Jíjà Nílẹ̀ Yorùbáysan.org/umgt/uploaded/186_Ipa_Pataki.pdf · 2018-10-08 · Ipa Pàtàkì tí Orín ń Kó Nínú Ètò Ogun

142

Ipa Pàtàkì tí Orín ń Kó Nínú Ètò Ogun Jíjà Níle Yorùbá

only a limited regard for strategy” (A� won ogun tı awon ja di

jıja laı nı eto kan gunmo).

Johnson (1921:156) kın oro awon onımo oke yıı leyın nıgba

tı o so pe:

There never was or has been a standing army, nor any trained soldiers (except at Ibadan latterly where the idea began to germinate, and some of the chiefs had a number of their slaves trained solely for war; some chiefs had also a corps of boys, not to bear arms, but to be attendant on them in battle, in order to farmiliarise them with the horrors of war!. Ko sı agbekale awon omo ogun kankan rı, bee ni ko sı akosemose omo ogun (yato sı eyı to wa nıgbeyıngbeyın nı I�badan nıbi tı ero naa ti bere sı ı hu jade, tı opo awon ıjoye sı nı opo eru tı won ko nı ogun jıja; opo awon ıjoye tun nı agbarıjo awon omokunrin, tı kı ı se lati gbe ohun ıja, sugbon lati wa pelu won loju ogun, nı ona a ti je kı won mo nıpa awon lalurı ogun!.

Orin yıı so aleebu awon jagunjagun E� gba, eyı sı mu kı awon

I�badan borı E� gba nıgba ogun naa. Abraham (1958:535) je

ka mo pe kı ı se E� gba nıkan ni awon I�badan segun nınu

ogun I�jaye naa, o nı I�jaye pelu forı sota ogun naa leyın tı

Kurunmı ku tan nı odun 1862. Ohun tı o so nıyı:

…from 1860 – 1862, I�jaye war raged, I�bıkunle (the Balogun of I�badon) destroying I�jaye. This

Page 13: Ipa Pàtàkì tí Orín ń Kó Nínú Ètò Ogun Jíjà Nílẹ̀ Yorùbáysan.org/umgt/uploaded/186_Ipa_Pataki.pdf · 2018-10-08 · Ipa Pàtàkì tí Orín ń Kó Nínú Ètò Ogun

143

Yorùbá: Journal of the Yorùbá Studies Association of Nigeria (Vol. 9 No. 1)

war was won by I�badon in 1862. Some months after the death of Kurunmı. …lati 1860 – 1862, Ogun I�jaye di jıja, I�bıkunle (Balogun I�badan) run I�jaye. I�badan ni o sı borı nınu ogun naa nı 1862 leyın osu dıe tı Kurunmı ti ku.

A� won jagunjagun I�badan tun korin kan bu awon

I�jebu nıgba tı won sıgun pade nıgba ogun I�peru. Orin tı

awon I�badan ko naa nıyı:

I�jebu ko pe okoo owo, Nıtorı eru la se n lo.

A� won jagunjagun I�badan fenu saata awon omo ogun I�jebu

nıgba ogun I�peru. I�dı tı I�badan �i fenu tenbelu I�jebu ni pe ko

sı ogun to pa awon mejeejı po tı awon I�badan ko ti segun

awon I�jebu.

A� won O� gbomoso korin kan nıgba ogun A� gbekoya tı o

waye nı odun 1968 sı 1970 nı O� gbomoso ati agbegbe O� yo.

Orin naa lo bayıı:

Orı muba ni o kun un Orı muba ni o kun un Koto kan gırıwo Tı n be lO� wode Orı muba ni o kun un

A� won ara ılu O� gbomoso forin oke yıı bu Baale Olajıde

Olayode (Soun O� gbomoso ıgba naa) tı o ko awon olopaa orı-

ırın (olopaa kogbereegbe) wa sı O� gbomoso lati I�badan kı

Page 14: Ipa Pàtàkì tí Orín ń Kó Nínú Ètò Ogun Jíjà Nílẹ̀ Yorùbáysan.org/umgt/uploaded/186_Ipa_Pataki.pdf · 2018-10-08 · Ipa Pàtàkì tí Orín ń Kó Nínú Ètò Ogun

144

Ipa Pàtàkì tí Orín ń Kó Nínú Ètò Ogun Jíjà Níle Yorùbá

won le da awon to n fehonu han nıpa ıwa ımotara-eni tı

Baale naa lorı sıse alekun iye owo-orı tara ılu n san tele

laıbıkıta ohun to le tibe yo. Loooto ni pe opo emı ara ılu lo lo

nınu ogun ohun, amo kı ı se awon nıkan, Baale ati opo awon

olopaa ati omo ogun to ko wa lati I�badan lo segbe sınu ogun

naa. Bı a ba n se e, ile aye lo n gbe, a kı ı se e n be lode orun

loro naa wa da.

Orin ajẹmógun nígbà tí Ogun jíjà bá parí

Orısrısi orin ajemogun ni awon omo ogun ati awon ara ılu

maa n ko nı kete tı ogun jıja ba ti parı. A� won orin wonyi

sabaa maa n kede pe ogun kan wa sopin tabı kı won kede

ısegun tı o fara han nınu ogun naa Won sı maa n �i orin

wonyı gborıyın fun awon jagunjagun lawujo Yoruba nı gere

tı ogun parı. O� kan lara awon orin bee ni eyı tı awon I�jebu ko

lati fıdunnu won han nıgba tı awon E� gba kede fun awon

I�jebu pe awon ko jagun mo nı asıko ogun O� wıwı. A� won

I�jebu ko orin naa lati �i bınu won se dun to han. I�dı ni pe

won ko fe kogun naa sıpa mo awon lowo, bee ni inu won

dun pe alaafıa a joba leyın ogun. Orin naa nıyı:

Omode I�jebu, E ku ewu. A� gba I�jebu, E ku ewu. O� te yıı jaja parı o. Johnson (1921:301)

O� mıran ni orin tı akewı Kurunmı ti I�jaye ko �i yin

Kurunmı nı kete togun Gbanamu parı. Orin ohun nıyı:

Page 15: Ipa Pàtàkì tí Orín ń Kó Nínú Ètò Ogun Jíjà Nílẹ̀ Yorùbáysan.org/umgt/uploaded/186_Ipa_Pataki.pdf · 2018-10-08 · Ipa Pàtàkì tí Orín ń Kó Nínú Ètò Ogun

145

Yorùbá: Journal of the Yorùbá Studies Association of Nigeria (Vol. 9 No. 1)

O� pa Maye, O� pa O� gını, O� pa Degesin, O� �i oko ti Ife laya. (ibid: 286)

A� won akewı Kurunmı ti ile I�jaye ko orin oke yıı lati gborıyın

fun oga won nıgba tı o segun awon ota re. Lara awon olorı

ogun tı Kurunmı pa nıgba ogun Gbanamu naa ni Maye

(Baale I�badan akoko, tı a gbo pe lati Ife lo ti wa), O� gını ati

Degesin sı je olorı omo ogun E� gba nıgba naa.

Iṣe Pàtàkì tí Orin ń ṣe Nínú Ètò Ogun Jíjà

Ise patakı ni awon Yoruba maa n �i awon orin ajemogun se

nınu eto ogun jıja nı awujo won. Yoruba maa n korin yıı lati

se korıya fun awon jagunjagun, lati kı won laya ati lati mu

won lokan le tı won ba n lo oju ogun (Adu ati Aderıbigbe,

2016:405). A� won ise patakı tı awon orin ajemogun wonyı n

se ko tan sıbe, a tun rı opolopo ipa patakı tı orin ogun maa n

ko nınu eto ogun jıja lawujo Yoruba. Orin ogun le sise

ıfehonuhan, ısote, ıpetusaawo, ıkılo, ıkede ogun sıse, ati bee

bee lo. Awe (1975:268) �i ipo patakı tı ewı alohun wa nınu

eto ogun jıja lawujo han nıgba to n soro nıpa orıkı:

In any exercise aimed at examining the nature of warfare among the Yoruba, one particular source cannot be overlooked. This is the orıkı, praise poem or citation on an object.

Page 16: Ipa Pàtàkì tí Orín ń Kó Nínú Ètò Ogun Jíjà Nílẹ̀ Yorùbáysan.org/umgt/uploaded/186_Ipa_Pataki.pdf · 2018-10-08 · Ipa Pàtàkì tí Orín ń Kó Nínú Ètò Ogun

146

Ipa Pàtàkì tí Orín ń Kó Nínú Ètò Ogun Jíjà Níle Yorùbá

Nı ıgbakuugba tı a ba gbıyanju lati se agbeyewo ogun jıja laarin awon Yoruba, orısun kan patakı ni a ko le foju pare. O� un naa ni orıkı, ewı ıgborıyın tabı ıpaato lorı nnkan kan.

A� mo kı ı se orıkı nıkan ni eyı bawı, lara awon tı o ku ni orin

tı a n gbe yewo nıbı. Adegboju (2016:429) je kı a mo ise

patakı tı awon orin ogun n se nınu eto ogun jıja nıle Yoruba

nıgba to so bayıı:

Lasıko ogun ni iru orin bayıı maa n waye lati le mu kı awon omo ogun o jı gırı kı orı won o le wule lati ja ajasegun loju ıja. Won a sı tun maa lo o lati �i se ajoyo leyın ısegun.

A� peere ise patakı tı awon orin ajemogun maa n se nınu eto

ogun jıja ni wonyı, gege bı o se han nınu eto ogun jıja nıle

Yoruba.

Ìforin ogun ṣìpe

I�ran Yoruba maa n forin sıpe nı asıko ogun jıja. Won le korin

kı won ma baa mu won mo awon tı yo pelu awon

jagunjagun lo sogun. I�dı ni pe won le ma pada darı wale mo.

Sebı ıbere ogun ni enıyan n mo, ko seni tıı mo opin re. A� won

Egba maa n korin kan nıgba tı won n jagun A� dubı. Ohun tı o

bı orin naa ni pe bı Ogun A� dubı se n ja lowo ni awon alase

ılu Abeokuta bı Alake Gbadebo, ati Adegboyega Edun, tı o je

Akowe ılu nıgba naa, n ko enikeni tı won ba fura sı pe o wa

Page 17: Ipa Pàtàkì tí Orín ń Kó Nínú Ètò Ogun Jíjà Nílẹ̀ Yorùbáysan.org/umgt/uploaded/186_Ipa_Pataki.pdf · 2018-10-08 · Ipa Pàtàkì tí Orín ń Kó Nínú Ètò Ogun

147

Yorùbá: Journal of the Yorùbá Studies Association of Nigeria (Vol. 9 No. 1)

nıdıı ote to bı Ogun A� dubı lo soju ogun laıse, laıro. Orin naa

lo bayıı:

E ma ma ran mi rA� dubı. Eni e ran lo, Ko ı bo o. Eni e ran lo, Ko ı de. Ajıkobi (2013:26)

Ogun A� dubı yıı ni won nı o waye laarin odun 1914-1918. O�

han pe asıko kan naa ni Ogun A� dubı ati Ogun A� gbaye akoko

waye.

A� won I�laaro ko orin kan sıpe sı awon afobaje ti ile

I�laaro nıgba tı awon omoye mu oro oba jıje nı ‘bı o ba a, o pa

a; bı o o ba a, o ju u nı kumo’. A� won ara ılu ko orin sıpe pe kı

awon afobaje gbe ade le eni to ye lorı. Nınu orin won ohun,

o han pe Omooba Adekunle ni oye naa to sı nıgba naa. Orin

tı won ko �i sıpe naa nıyı:

Bo ba je bee nıı ba maa da, Ka moye f’A� dekunle o. E� dudu Oba I�bese Iku e lo pa O� tenkan I�yen o to mu sogbon dan E n yanko �iri�iri.

Won �i orin oke yıı sıpe kı ogun ‘ta ni oye to sı’ le rokun

ıgbagbe, kı alaafıa le joba nı ılu.

I�joye kan lati Ife tı o forı pekun sı I�badan, tı o sı tun je

olorı jagunjagun korin kıgbe sıpe sı awon tı won mu un nı

ıgbekun nıgba Ogun Gbanamu pe kı awon ıjoye I�badan ati

Page 18: Ipa Pàtàkì tí Orín ń Kó Nínú Ètò Ogun Jíjà Nílẹ̀ Yorùbáysan.org/umgt/uploaded/186_Ipa_Pataki.pdf · 2018-10-08 · Ipa Pàtàkì tí Orín ń Kó Nínú Ètò Ogun

148

Ipa Pàtàkì tí Orín ń Kó Nínú Ètò Ogun Jíjà Níle Yorùbá

awon olorı ogun yooku ma se da ıgbejo re se, kı won �i oju

re kan Lakanle tı o je Alase awon O� yo tı o wo sı I�badan leyın

tı Oorun ati Gbagura fo. Won mu un nıgbekun nıtorı pe o pa

ara O� yo kan lona aıto, o sı sa kuro nı ılu. Orin tı o ko sıpe naa

nıyı:

E ma da a se, E �i oju mi kan alagba! E ma da a se, E �i oju mi kan Lakanle. Johnson (1921: 286)

Yoruba bo, won nı ‘ko seni tı Olorun ko le mu’. Maye ro pe

oun le muwa ıbaje re je, amo oro gboju kejı yo sı i. Omo

ogun lasan, tı kı ı se olorı ogun lo mu Maye nıgbekun tı o sı

be e lorı.

Ìforin ogun kéde ogun jíjà

Nıle Yoruba, orin ni ohun patakı akoko tı won �i maa n mo

pe awon ılu kan fe dıde ogun sı ara won. O� maa n han nınu

orin won pe won fe lo doju ogun ko awon enıyan kan tabı

ılu kan. Iru awon orin wonyı ni a le so pe won �i n kede ogun

jıja. Nınu ote to waye laarin awon Elekoo meta (Elekoo

E� sugbayı Dosumu, Elekoo I�bıkunle Akıtoye, ati Elekoo

Sanusı Olusı) bı o se han nı Ajıkobi (2013:40-41), awon

omo Kosoko korin sı gangan lo sı I�ga I�dunganran nıgba tı

won gbo pe Oba Oluwole da serıa fun eru Kosoko kan nı I�ga.

Orin tı won ko naa nıyı:

B’o le d’ogun ko d’ogun.

B’o le d’ote ko dote.

Page 19: Ipa Pàtàkì tí Orín ń Kó Nínú Ètò Ogun Jíjà Nílẹ̀ Yorùbáysan.org/umgt/uploaded/186_Ipa_Pataki.pdf · 2018-10-08 · Ipa Pàtàkì tí Orín ń Kó Nínú Ètò Ogun

149

Yorùbá: Journal of the Yorùbá Studies Association of Nigeria (Vol. 9 No. 1)

O� jo p’ewee koko, Bo le ya, ko ya.

Oba Oluwole lo pada borı ote naa, Kosoko sı sa kuro nı E� ko

lo sı A� pa nıgba naa.

Ìforin ote ṣáátá otá ẹni

Yoruba maa n forin ote bu enu ate lu ota won nıgba ogun

jıja. E� yı sı maa n waye nıgba tı ohun tı ota ba ro sı eni tı won

n dıte mo ba ja sı pabo. A� peere irufe orin bee ni eyı tı awon

olufe Baale Otunla tı o je omo Baale O� jo Aburumakuu ti

O� gbomoso gba ona eburu gorı oye laı�i ti awon ıjoye ılu se

leyın iku baba re. A� won ore ati olufe Baale Otunla ko orin

naa nıgba tı won gbo pe awon ıjoye ılu fe ro Baale Otunla

loye lati �i bu enu ate lu ıwa tı awon ıjoye fe hu nıgba naa. Nı

otıto, kı ı se Baale O� tunla ni o kan lati gun orı apere nı ıgba

naa bı ko se Baale Gbagun Ajagungbade I. Orin tı won ko nı

ıgba naa lati �i enu saata awon ıjoye ılu nıyı:

Iro ni won n pa, E� ke ni won n se. O� dijo e ba fate meja lodo, Kı e to roba mu.

Aawo yıı waye nı aarın odun 1869 ati 1870. I�gba tı ılu o fara

ro fun Baale O� tunla ati awon emewa re mo ni Baale Otunla

sa kuro lorı oye tı o sı �i ılu O� gbomoso sıle. Kı ı se oju booro

ni won �i gba omo nı owo ekuro Baale O� tunla, awon

jagunjagun O� gbomoso tı o n ran awon I�badan lowo nınu

Page 20: Ipa Pàtàkì tí Orín ń Kó Nínú Ètò Ogun Jíjà Nílẹ̀ Yorùbáysan.org/umgt/uploaded/186_Ipa_Pataki.pdf · 2018-10-08 · Ipa Pàtàkì tí Orín ń Kó Nínú Ètò Ogun

150

Ipa Pàtàkì tí Orín ń Kó Nínú Ètò Ogun Jíjà Níle Yorùbá

ogun Ilesa nı lati pada wa sı ile lati yanju oran naa. E� yı sı mu

kı aawo be sıle tı Baale O� tunla sı fılu sıle. Ni awon ıjoye ba

gbe Baale Gbagun gorı oye.

A� won Yoruba tun maa ko orin bu enu ate lu ero awon

won nı ıgba ti ota ba ro pe ogun kan maa gbe won lo tı o sı

je pe won pada se ogun naa tı oro wa di pe ‘Eni a ro pe ko le

pago, wa di eni to n ko ile alaruru’ nı ıgbeyın. Iru orin bee ni

re e:

Ko wo, Ko wo A� raba o wo mo, Oju tıroko!

Orin naa �i han pe ohun tı ota gbero ko se nı orı eni tabı

awon tı o ko orin naa.

Ìforin ogun ṣe Iṣe Kóríyá fún àwọn Jagunjagun

Nı opo ıgba nı awon Yoruba maa n korin ogun mu orı awon

jagunjagun ya sı ogun jıja kı won le segun ota. Won sı maa n

�i iru orin bee se ise ımulokan le fun awon omo ogun won.

A� peere iru orin bee ni eyı tı O� gunmola ti I�badan ko nıgba tı

o gesin lo sabewo sı awon omo ogun I�badan nıgba ogun

I�jaye pe:

I�bıkunle, A o se won, A o se won, E� gba ko mo ogun jıja, A o se won.

Johnson (1921:414)

Page 21: Ipa Pàtàkì tí Orín ń Kó Nínú Ètò Ogun Jíjà Nílẹ̀ Yorùbáysan.org/umgt/uploaded/186_Ipa_Pataki.pdf · 2018-10-08 · Ipa Pàtàkì tí Orín ń Kó Nínú Ètò Ogun

151

Yorùbá: Journal of the Yorùbá Studies Association of Nigeria (Vol. 9 No. 1)

Orin yıı se korıya fun awon jagunjagun I�badan, nıtorı pe

O� gunmola ti forin so aleebu awon omo ogun E� gba.

Orin mııran tı awon Yoruba maa n ko kı ara awon omo ogun

le ya fun ogun jıja ni eyı tı won nı Kunrunmı tı o je A� are-O� na

Kakanfo ile Yoruba nıgba kan rı maa n ko nı ıgba tı Olorı

omo ogun naa ba n lo sı ogun. A� won onılu ati ara ılu ni won

nı o maa n ko orin ohun la�i �i mu A� are Kunrunmı pe o ti di

oorun tı o n gbonna janinjanin tı ota kan ko le sıju wo, tı o sı

n jo awon ota re lara. Orin ohun nıyı:

Kunrunmı doorun, O� gbonna janinjanin. A� are doorun, O� gbonna janinjanin.

Iru wonyı maa n mu orı awon ya lati lo sı oju ogun ni, eyı

yoo sı mu kı won le �i gbogbo agbara won ja ogun naa. I�dı ni

pe bı won ba segun, orıyın a tun po sı I ni.

Ìforin ogun fehónú hàn

A� won Yoruba maa n korin lati fehonu han lodı sı ohun tı

awon owo enıyan kan ba n se nı awujo won tı ko dara. E� yı sı

maa n waye nıgba tı aawo ba wa, yala laarin awon owo mejı

nı ılu kan tabı laarin ılu mejı tı won n ba ara won ja. A� peere

eyı ni orin tı awon I�seyın ko lati �i ko ıwosı tı ıjoba ile Geesı

�i lo won nıpa owo-orı sısan fun Oba Geesı eyı o ran Captain

Ross lati maa se nı agbegbe Ekun O� yo ati ılu O� yo nı odun

1916. Nınu orin naa I�seyın ko jale pe awon o san ısakole

Page 22: Ipa Pàtàkì tí Orín ń Kó Nínú Ètò Ogun Jíjà Nílẹ̀ Yorùbáysan.org/umgt/uploaded/186_Ipa_Pataki.pdf · 2018-10-08 · Ipa Pàtàkì tí Orín ń Kó Nínú Ètò Ogun

152

Ipa Pàtàkì tí Orín ń Kó Nínú Ètò Ogun Jíjà Níle Yorùbá

kankan fun Ajele Captain Ross, won nı Aseyın ni ısakole

awon to sı. Orin tı won ko nı ıgba naa nıyı:

Ara O� yo mOba, I�seyın ni o mOba. Ara O� yo mOba, I�seyın ni o mOba. E� eyan dudu to pe Roosı lejo. Ara O� yo mOba, I�seyın ni o mOba.

Orin yıı �i ye wa pe awon O� yo mo Oba ile Geesı nıtorı pe

won n san ısakole fun Ajele Ross tı o wa nı ekun naa bı asoju

Oba Geesı, amo, I�seyın ko mo on nıtorı won ko lati san

ısakole fun Ajele, tı won sı n ko ısakole to Aseyın lo. E� yı di

ogun di oran debi pe I�joba Geesı �i panpe o�in mu awon

Olorı ogun ati awon akoni I�seyın tı o ko ıyanje naa.

Ìforin Ogun ṣe Ìkìlo

A� won ayan maa n fılu korin kılo fun enikeni to ba n dasa

kogun sele lawujo Yoruba. Iru orin bee ni:

Bo ba buru tan, Tıe nıkan ni yo da. Bo ba buru tan, I�wo nıkan ni yo ku.

A� mo, opo aletı lapa eda ni kı ı gbo iru ıkılo ati ımoran awon

onılu yıı, a fıgba togun ohun ba mu won roko-ete aremabo.

Page 23: Ipa Pàtàkì tí Orín ń Kó Nínú Ètò Ogun Jíjà Nílẹ̀ Yorùbáysan.org/umgt/uploaded/186_Ipa_Pataki.pdf · 2018-10-08 · Ipa Pàtàkì tí Orín ń Kó Nínú Ètò Ogun

153

Yorùbá: Journal of the Yorùbá Studies Association of Nigeria (Vol. 9 No. 1)

A� peere orin ogun ajemokılo ni eyı tı won ko kılo fun

Balogun Popoola tile O� gbomoso tı o han nınu Oyerınde

(1934) eyı tı Olatunjı (1984:83) se amulo:

Bı won n lerı ogun, Ma se ba won lerı ogun mo; Bı won n soro ıja, Ma se ba won soro ıja mo. A kı ı soro ıja loju eni tı ko le e nani.

Won gba Balogun Popoola nı ımoran pe ko ma se dara po

mo awon ota ılu to n gbımo kogun sele nıluu. Orin yıı je ka

mo pe awon ara ılu fe kı Balogun Popoola yera fun awon

olote to fe gbomi ogun lena. O� sı han nı ıla to gbeyın pe

awon olote naa o nı agbara lati segun bı ogun ba tile sele.

Àgbálọgbábo

A ti ye ipa patakı tı orin n ko nınu eto ogun jıja lawujo

Yoruba wo nınu apileko yıı. O� sı han pe awon Yoruba ko

koyan orin kere lawujo won. Orin sı nıyı, okun emı ogun jıja

lo je nıle Yoruba. Ipo kolegbe tı orin dı mu nınu eto ogun jıja

lawujo Yoruba nılati ye teru-tomo, kı awujo le goke agba, kı

alaafıa ati ırepo sı le joba nıle Yoruba ati lorıle-ede Naıjırıa

lapapo. Ko ye kı a gbagbe awon ısele to bı awon ogun to

waye nıle Yoruba, kı a ma baa tun pada sı ese aaro.

I�wadıı gbodo jinle nıpa awon ısele ana, kı a le se

atunse sı awon kudıe-kudie to sele nı ana to n se akoba fun

ojo onı awujo Yoruba, to sı le nı ıpalara fun ojo ola awujo

Yoruba nıpa wıwo ipa tı awon orin tı won lo ko nınu awon

Page 24: Ipa Pàtàkì tí Orín ń Kó Nínú Ètò Ogun Jíjà Nílẹ̀ Yorùbáysan.org/umgt/uploaded/186_Ipa_Pataki.pdf · 2018-10-08 · Ipa Pàtàkì tí Orín ń Kó Nínú Ètò Ogun

154

Ipa Pàtàkì tí Orín ń Kó Nínú Ètò Ogun Jíjà Níle Yorùbá

ısele naa. Yoruba nı bomode ba subu, a wo iwaju; ıran agba

to subu nıı weyın wo kıru ısubu bee ma baa le waye mo.

I�feegun O� tolo to awon oro ati ısele to le daawo,

dogun dote nı ıtunbı-n-nubı ni o le mu awujo toro.

Eleyameya ko dara rara, o n so awujo di isa oku ni.

Ìwé Ìtokasí

Adebajo, O. (2016). ‘A� won Orin Fıımu Ṣaworo-Idẹ ati Agogo Èèwo Gege bı Awojıji I�sele Ile Wa’ nınu Adeleke, D. (Olootu) Àṣà, Èrò àti Èdè Nínú Iṣe-Ọnà Aláwòmo-Lítíréṣo Akínwùmí Ìṣolá. I�badan: DB Martoy Books, pp. 245-259.

Adegbodu, O. (2016). ‘I�lo Orin nınu awon ıwe A� tinuda Akınwumı I�sola’ nınu Adeleke, D. (Olootu) Àṣà, Èrò àti Èdè Nínú Iṣe-Ọnà Aláwòmo-Lítíréṣo Akínwùmí Ìṣolá. I�badan: DB Martoy Books, pp. 423-431.

Adeoye, C. (2005). Àṣà àti Ìṣe Yorùbá. I�badan: University Press PLC.

Adeyemı, O. (2006). Tíorì Lítíréṣo ní Èdè Yorùbá. I�jebu-O� de: Sebıotimo Publications.

Akınyemı, A. ati Ajıbade, O. (2016). ‘I�lo Lıtıreso Alohun Nınu Ogún Ọmọdé nınu Adeleke, D. (Olootu) Àṣà, Èrò àti Èdè Nínú Iṣe-Ọnà Aláwòmo-Lítíréṣo Akínwùmí Ìṣolá. I�badan: DB Martoy Books, pp. 295-306.

Adu, O. ati Aderıbigbe, M. (2016). ‘I�lo Orin nınu A� won Fıımu A� gbelewo Akınwumı I�sola nınu Adeleke, D. (Olootu) Àṣà, Èrò àti Èdè Nínú Iṣe-Ọnà Aláwòmo-Lítíréṣo

Page 25: Ipa Pàtàkì tí Orín ń Kó Nínú Ètò Ogun Jíjà Nílẹ̀ Yorùbáysan.org/umgt/uploaded/186_Ipa_Pataki.pdf · 2018-10-08 · Ipa Pàtàkì tí Orín ń Kó Nínú Ètò Ogun

155

Yorùbá: Journal of the Yorùbá Studies Association of Nigeria (Vol. 9 No. 1)

Akínwùmí Ìṣolá. I�badan: DB Martoy Books, pp. 402-410.

A� jayı, A. and Smith, R. (1971). Yoruba warfare in the nineteenth century. Ibadan: Ibadan University Press.

Ajıkobi, O. (2013). Ipa tí Orín kó Nínú O� te Elékòó Meta. Lagos: The Graphics Men.

________ (2000). Oyínkán Ṣe Bẹbẹ. Lagos: Prompt Books.

Bamidele, L. (2000). Literature and Sociology. Ibadan: Stirling Horden Publishers Nigeria Limited.

Bleich, D. (1978). Subjective Criticism. Baltimore and London: Johns Hopkins University Press.

Fajenyo, S. (2016). ‘A� gbeyewo I�lo Ewı Alohun Yoruba Nınu Efunsetan Anıwura tı Akınwumı I�sola Ko’ nınu Adeleke, D. (Olootu) Àṣà, Èrò àti Èdè Nínú Iṣe-Ọnà Aláwòmo-Lítíréṣo Akínwùmí Ìṣolá. I�badan: DB Martoy Books, pp. 153-161.

Finnegan, R. (2012). Oral literature in Africa. United Kingdom: Open Book Publishers CIC Ltd.

Gbadamosı, O. (1980). Literary study of political songs in Yorùba. B. A. Long Essay, Department of African Languages and Literatures, University of Lagos, Lagos.

I�lorı, E. (2017). ‘Lıtıreso ati O� na I�banisoro I�gbalode: A� �ihan re nınu I�tan A� roso Ká Rìn Ká Po nınu Adenıyı A� kangbe (Olootu)YORÙBÁ: Journal of Yorùbá Studies Association of Nigeria, Vol.8, no. 4, pp.160-177.

I�sola, A. (2008). Ṣaworoidẹ. I�badan: University Press Plc.

Page 26: Ipa Pàtàkì tí Orín ń Kó Nínú Ètò Ogun Jíjà Nílẹ̀ Yorùbáysan.org/umgt/uploaded/186_Ipa_Pataki.pdf · 2018-10-08 · Ipa Pàtàkì tí Orín ń Kó Nínú Ètò Ogun

156

Ipa Pàtàkì tí Orín ń Kó Nínú Ètò Ogun Jíjà Níle Yorùbá

Johnson, S. (1921). The History of the Yorubas. Lagos: CSS Bookshops Limited.

Lawrenson, D. ati Swingwood, A. (1971). The Sociology of Literature. London: Mac Gobbon and Kee.

Olatunjı, O. (1984). Features of Yorùbá Oral Poetry. I�badan: University Press PLC.

Osoba, B. (2012). ‘Songs in Yoruba Drama: Illustration from Selected Yoruba Home Videos’ nınu Ihafa: Journal of African Studies, Vol. 5 No 4, pp.157-173.

O� woade, S. (2013). Pàtàkì Ogunòjàlú sí Ìlú Ògbómoṣo. I�we A� sekagba fun Oye Bı-EE� , Department of Linguistics, African and Asian Studies, University of Lagos, Lagos.

__________ (2017). Oral Yorùbá Poetry in Ògbómoṣo Traditional Political System. M. A. Thesis, Department of Linguistics, African and Asian Studies, University of Lagos, Lagos.

Sotunsa, M. (2009). Yorùbá Drum Poetry. London: Stillwatersstudios.